Wo Kábíyèsì Alafo ti ìlú Afo tí í ṣe ọba alayé tó pẹ́ lórí oyè jùlọ lọ́wọ́ yìí nílẹ̀ Yorùbá

Àkọlé fídíò, Wo ọba alayé tó pẹ́ lórí oyè jùlọ lọ́wọ́ yìí nílẹ̀ Yorùbá
Wo Kábíyèsì Alafo ti ìlú Afo tí í ṣe ọba alayé tó pẹ́ lórí oyè jùlọ lọ́wọ́ yìí nílẹ̀ Yorùbá
Aworan Ọba Adegoke Egunjobi Stephen,

Ọba Adegoke Egunjobi Stephen, Alafo ti ilu Afo nipinlẹ Ondo ni iwadii ti fihan pe oun ni Ọba to pẹ lori oye julọ ninu awọn ọba to ṣi wa laye bayii nilẹ Yoruba.

Kabiyesi Alafo ti ilu Afo gori apere baba nla rẹ ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kẹta ọdun 1958, eyi to tumọ si pe o ti pe ọdun mẹrindinlaadọrin ti Ọba Adegoke ti gori oye.

''Ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni mi nigba ti mo jọba lọdun 1958.

O ti pe ọdun mẹrindinlaadọrin bayii ti mo ti gori itẹ awọn baba nla mi.

Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun tori kii ṣe agbara mi, bi ko ṣe agbara Ọlọrun.

Ọlọrun ni o bami rinrin ajo naa.

Lẹyin ile ẹkọ alakọbẹrẹ, mo wa ni ‘’LA Modern School’’ niluu Owo nigba ti mo jẹ ọba.

Bi babalawo ba ji, bi ọlọpẹlẹ ba ji laarọ, Ọlọrun ni wọn a kọkọ juba fun un.

O tumọ si pe Ọlọrun lo fun wọn ni agbara lati maa ṣe iru iṣẹ yẹn, ti a dẹ maa fi ọna han awọn araye,'' Kabiyesi Alafo lo sọ bẹẹ.

Oba Adegoke ni ''ipo ọba ipo ẹlẹgẹ ni o.

Ẹnikẹni ti ko ba le ṣe e daadaa, ko yẹ ki o wa nibẹ.

Ki n to jẹ ọba, mo maa n gba bọọlu daadaa, ṣugbọn n ko le ṣe bẹẹ mọ lẹyin ti mo jọba tan.

Awọn ọpọlọpọ nnkan ti ko yẹ ki a ṣe, tabi pe a n rinde oru kaakiri igboro, tabi ki eeyan maa lọ buka lati jẹun tabi mu ọti, ko gbọdọ ribẹ pẹlu ọba.

Ọba ti o ba n ṣe bẹẹ n fi ara rẹ wọlẹ.

Bi ọba be fẹ jẹun, o ni lati wọ iyẹwu ni.''

Kabiyesi Alafo wa rọ awọn to ba de ori apere ọba pe ki wọn tẹ ẹ jẹjẹ ki wọn ba le rin jina.