Àwọn ọ̀dọ́ fárígá lórí yíyọ owó ìrànwọ́ orí epò, wọ́n ṣe ìwọ́de l‘Ekiti

Awon ọdọ orílè-èdè Nàìjíríà, ẹka ti ipinlẹ Ekiti, tí ké sí ìjọba àpapọ̀ àti Gomina ipinlẹ Ekiti, lati ṣé idasilẹ ẹka ileesẹ ti yoo maa se amojuto àwọn Ọdọ́ lawọn gbogbo ile isẹ ijọba àpapọ̀ ati ni ipinlẹ naa.
Awọn ọdọ naa tun rọ ijọba láti ṣe ètò ìdásẹ̀silẹ yanturu fún àwọn ará ilu ati pípèsè awọn ilé ìṣẹ ńláńlá fún ìgbé ayé irọrun ni Ipinlẹ Ekiti gẹgẹbi ọna àbáyọ lórí yiyọ Owo-ori epo kuro.
Arákùnrin Segun Famuyibo tí ó jé alága ẹgbẹ́ awọn ọdọ yika Naijiria, (National Youth Council of Nigeria) NYCN, ni Ipinle Ekiti lo pe ipe yi lojo Aje Monde lasiko ti won n se ayeye iranti ọjọ́ ìjọba tiwantiwa ti ọdún 2023 to wáyé nílùú Ado-Èkìtì.

Awọn ọdọ naa gba àwọn oloselu ni ìmọ̀ràn láti má rii dájú pé wọn ṣe ohun tí ó tọ fún anfaani ijọba tiwantiwa nitori ọfiisi wọn gẹ́gẹ́ bí oloselu ni asiko ọjọ ti yio pari.
Wọn ṣàlàyé irubọ awọn ti wọn ja fun ijọba tiwantiwa pẹlu ẹnití ó kọ́kọ́ jawe olubori ninu idibo aarẹ oṣu kẹfa ọjọ Kejìlá ọdún 1993, Moshood Abiọla ko yẹ ki o jẹ asan.
Wọn sọ pe ijọba tiwantiwa jẹ ijọba ti o dara julọ ti wọn si pàrọwà fun gbogbo awọn ọmọ Naijiria lati rii daju pe aṣeyọri ba ijọba tiwantiwa ni orilẹ-èdè Nàìjíríà.
Bakana ni alaga egbe Ọdọ́ National Youth Council of Nigeria sọ pe Mko jẹ aami ti ijọba tiwantiwa ni Naijiria ti wọn si gba ijọba apapọ ati ti ipinlẹ Naijiria lati ri dájúdájú pé àwọn ọdọ ni ipá tí ó pò nínú ìṣejọba.












