Boniface àtàwọn agbábọ́ọ̀lù míì tí wọ́n kùnà láti darapọ̀ mọ́ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù míì torí àyẹ̀wò ará wọn foríṣánpọ́n

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Erongba ẹlẹsẹ ayo ọmọ Naijiria, Victor Boniface, lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu AC Milan lati Bayer Leverkusen foriṣanpọn lẹyin ti esi ayẹwo ara rẹ ti wọn ṣe ko kẹsẹjari.
Boniface ko ni le darapọ mọ AC Milan tori ẹgbẹ agbabọọlu naa sọ pe ko pegede ninu ayẹwo ti wọn ṣe lori ara rẹ.
Ṣaaju ni Leverkusen ati AC Milan ti fẹnuko lori adehun wi pe Boniface yoo wa ni AC Milan fun saa bọọlu kan fun €5m.
O tun wa ninu adehun naa pe AC Milan le ra Boniface patapata fun €24m ti o ba gba bọọlu fun wọn tan fun saa kan.
Ohun ti a gbọ ni pe orunkun Boniface lawọn dokita Milan ti ṣe ayẹwo to pọ.
Ti ẹ o ba gbagbe, lori orunkun yii naa ni Boniface ti ṣeeṣe ni saa bọọlu 2018/2019 ati 2020/2021.
Nicolas Jackson
Agbabọọlu mii ti ayẹwo ara rẹ forisanpọn ni Nicolas Jackson.
Ẹgbẹ agbabọọlu Villarreal ati Bournemouth ti fẹnuko lori ẹlẹsẹ ayo naa wi pe yoo darapọ mọ Bournemouth loṣu Kinni ọdun 2023.
Amọ, adehun naa foriṣanpọn lẹyin ti Bournemouth sọ pe Jackson ti ṣeṣe lori iṣan to w ani itan rẹ.
Ṣugbọn Jackson pada darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lẹyin oṣu mẹfa ti erongba rẹ lati lọ Bournemouth foriṣanpọn.
Jackson ti gba ife ẹyẹ Europa Conference League ati FIFA Club World Cup pẹlu Chelsea bayii.
O si ṣeeṣe ki o tun fi ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea silẹ laipẹ tori o dabi ẹni pe wọn fẹ ta a.
Hakim Ziyech
Hakin Ziyech ni agbabọọlu Chelsea mii ti ko lanfaani lati darapọ ikọ agbabọọlu Al-Nassr lọdun 2023 lẹyin ti ko pegede ninu ayẹwo ara rẹ ti wọn ṣe fun un.
Ohun ti ẹgbẹ agbabọọlu Al-Nassr sọ ni pe nkankan wa ninu orunkun rẹ ti ko duro daadaa.
Lẹyin naa ni Ziyech pada si Chelsea ti o si darapọ mọ Galatasaray lorilẹede Turkey.
Loic Remy
Agbabọọlu iwaju Loic Remy ko ba darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lọdun 2014.
Ṣugbọn eyi foriṣanpọn lẹyin ti awọn dokita Liverpool ri pe nnkankan ko ṣe daadaa ninu ọkan Remy.
Amọ, Remy pada darapọ mọ Chelsea lẹyin oṣu mẹfa si asiko naa.
Koda, Remy gba ife ẹyẹ Premier League pẹlu Chelsea ni saa akọkọ to lo ni Chelsea.
Demba Ba
Ni ẹgbẹ agbabọọlu meji ọtọọtọ ni ẹlẹsẹ ayo ọmọ orilẹede Senegal ti kuna nibi ayẹwo ara rẹ ti o ṣe.
Akọkọ ni ẹgbẹ agbabọọlu Germany, Stuttgart, nibi ti ayẹwo ara Demba Ba ti foriṣanpọn.
Lẹyin naa ni ayẹwo ara rẹ tun foriṣanpọn lọdun 2009 ati 2011.
Bo tilẹ jẹ pe ayẹwo ara Demba Ba foriṣanpọn lawọn ẹgbẹ agbabọọlu kan, o si pada gbabọọlu lawọn ẹgbẹ agbabọọlu to gbaju gbaja to fi mọ Chelsea.
Ivan Toney
Ẹlẹsẹ ayo England naa wa lara awọn agbabọọlu ti ayẹwo ara wọn ko kẹsẹjari lawọn asiko kan.
Toney kuna lati darapọ mọ Wolverhampton Wanderers lẹyin ti ayẹwo ara rẹ foriṣanpọn.
Amọ, o pada darapọ ikọ agbabọọlu Newcastle lẹyin o rẹyin.
Ẹgbẹ agbabọọlu Al-Ahli lo n ṣoju lọwọ yii lorilẹede Saudi Arabia















