Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jápa ẹ ṣọ́ra kí wọ́n má baà jà yín ní olè – Lai Mohammed

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ijọba apapọ lorilẹede Naijiria ti gba awọn ọmọ Naijiria ti wọn n lọ si oke okun ni imọran lati ṣọra ṣe ki wọn ma ja wọn ni ole.

Minisita fun eto iroyin ni Naijiria, Lai Mohammed lo fun awọn ọmọ Naijiria ni imọran yii nibi ipade lati jiroro lori igbeṣẹ aarẹ Buhari lati mu idagbasoke ba orilẹede Naijiria.

Ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ iroyin ni wọn n ṣakoso ijiroro naa ti wọn pe ni ‘President Muhammadu Buhari (PMB) Administration Scorecard 2015-2023 Series’.

''Awọn ole ti pọ ni oke okun ẹ ṣọra ṣe''

Ninu ọrọ rẹ, Muhammed ni awọn gba awọn ọmọ Naijiria ni imọran naa nitori awọn ti gba ọpọlọpọ ipe lori bi wọn ṣe n ja awọn eniyan ni ole.

Minisita naa ni awọn iṣẹlẹ yii ti kọja keremi ni awọn sẹ dasi ọrọ naa ni asiko yii.

‘’Ẹleyii to ṣẹlẹ laipẹ yii ni awọn to n rinrinajo lọ si Ilẹ Gẹẹsi, ti wọn si ji eru wọn gbe lọ ni awọn ile itaja to fi mọ agbegbe Oxford ni ilu London.

Eyi lo jẹ ki a gba awọn ọmọ Naijiria ni imọran pe ki wọn ṣọra ṣe ni oke okun paapaa awọn to n lọ si Yuroopu, USA ati Ilẹ Gẹẹsi’’

''Amọran lasan ni a gba yin ki wọn ma baa lu yin ni jibiti ni oke okun, nitori ole jija ati gbewiri ti peleke si ni awọn ilẹ okeere.''