Wo aṣọ Diana Olorì tẹ́lẹ̀ rí Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Charles tí ẹnìkan rà ní N878m

Aso Diana

Suẹta kan ti Olori Diana, iyawo tẹlẹri Ọba ilẹ Gẹẹsi Charles ni ẹnikan ti rà ní owo to le ni ẹgbẹrin miliọnu(N878m).

Nibi ipatẹ ọja to wáyé niluu New York l'Amẹrika ni ẹni naa ti ra aṣọ yii lẹyin to da owo to pọ julọ le aṣọ naa.

Lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹjọ ni wọn gbe aṣọ naa sita fún tita ti awọn eeyan si bẹrẹ lati maa k'owo lee.

Ileeṣẹ itaja Sotheby's ti kọkọ diye le aṣọ naa pe ẹgbẹrun lọna aadọta owo dọla($50,000) sí ọgọrin l'awọn yoo ta a kì wọn to ri ẹni to ra a ni N878m.

Amọ, ileeṣẹ Sotheby's ko darukọ ẹni to ra suẹta ọhun ni owo iyebiye.

Ẹwẹ, ilumọọka arinrin-oge, Kim Kardashian ti kọkọ ra aṣọ Diana to ni ami agbelebu Attallah ni owo to le ni ẹgbẹrun lọna igba($203,000) nibi ipatẹ ọja to waye loṣu kinni ọdun 2023 yii.

Ọpọ eeyan lo maa n ri suẹta ti ẹnikan ra yii gẹgẹ bii ami ipo ti Diana wa ni idile ọba ilẹ Gẹẹsi.

Ṣugbọn awọn onimọ nipa itan gbagbọ pe Diana kan wọ aṣọ lasan ni, aṣọ naa ko niiṣe pẹlu ipo rẹ nile ọba ilẹ Gẹẹsi.

Awọn onimọ nipa itan sọ pe o ṣeeṣe ki Diana fi aṣọ naa polowo ileeṣẹ "Sloane Ranger" pẹlu aṣọ naa.

Ki ẹrọ igọrọkaye to de, aworan Diana ninu suẹta yii polowo ileeṣẹ to ṣe aṣọ naa.

Lẹyin igbeyawo rẹ ni aafin Buckingham kọ lẹta si ileeṣẹ to ṣe aṣọ naa ki o ṣe atunṣe rẹ tabi rọpo rẹ tori o ti bajẹ.

Lẹyin naa ni Diana wọ aṣọ mii ti wọn fi rọpo eyi to n lo tẹlẹ, koda eyi ti won ṣẹṣẹ ṣe ni o wọ lọ sibi ere idaraya ori ẹsin lọdun 1983.

Ileeṣẹ ontaja Sotheby's fi lẹta ti aafin Buckingham kọ sí ileeṣẹ Warm and Wonderful sori suẹta ọhun.

Bakan naa ni wọn tun dupẹ lọwọ ileeṣẹ naa fun atunṣe aṣọ Diana lẹyìn igbeyawo rẹ.