Wọ́n ṣàwárí ṣọ́ọ̀ṣì tó ń lé ẹ̀mí burúkú jáde nínú ọmọdékùnrin kan ní UK

- Author, By Katie Mark
- Role, BBC Panorama
Ẹka ile ijọsin kan ni UK ni wọn ti ṣe awari rẹ lasiko ti wọn n gbiyanju lati le ẹmi aimọ kuro nlnu ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan.
Ile ijọsin Universal Church of Kingdom of God ni wọn rí ti ní wọn ń fedefọ awọn ọrọ nla lati fi le ẹmi buruku naa kuro.
Ile ìjọsin UCKG ni ẹnikẹni ti ko ba ti pe ọmọ ọdun mejidinlogun ko ni anfani sì awọn adura nla.
Iwadii Ileeṣẹ BBC Panorama ree.
Ile ijọsin sọ fun awọn olùjọsìn rẹ pe o le se iranlọwọ ohun to n ba ọkan jẹ wọn nípa líle ẹmi buruku jade.
Ile ijọsin UCKG ni ẹka kaakiri agbaye, pẹlu ẹka marundinlogoji ni ilẹ UK níbi tí wọn forukọ silẹ gẹgẹ bii ileeṣẹ to n pese iranlọwọ.
O ni olùjọsìn ẹgbẹrun mẹwaa kaakiri orilẹede UK, to si n pe ara rẹ ní ile ijọsin igbalode.
Adura lati le ẹmi buruku jade ni ko wọpọ ni ile ijọsin Kristẹni lagbaye.
Dokita Joe Alfred, Bíṣọọbu to n sisẹ lati se atunse asa Kristẹni.
"Awọn ile ijọsin ni England ni líle ẹmi buruku jade lati ẹka wọn. Ibeere wa ni pe bí wọn sese
Adura nla ti UCKG yii ni Pasitọ ma gbe ọwọ le awọn olùjọsìn lori tí yoo si ma pàṣẹ fún ẹmi okunkun lati jade kuro lara wọn.
Ile ijọsin ni awọn n se eto adura nla yii lati fọ ẹmi awọn eeyan mọ ati lati tan isoro wọn.

Ile ijọsin UCKG bẹrẹ si ma wo gau lẹyin ti ọmọ mẹjọ kan, Victoria Climbie, ẹni tí ẹgbọn iya rẹ ati ọrẹ rẹ ọkùnrin ṣekupa.
Ni o ku ọsẹ kan to ma jade ni ẹgbọn iya rẹ ati ọrẹ ọkùnrin gbe Victoria lọ sí ẹka ile ijọsin.
Pasitọ ni oun ro pe ẹmi buruku lo wa ninu ọmọ naa, ti oun si rọ wọn lati gbe lọ síbi isọji adura nla sugbọn kí adura naa to bẹrẹ Pasitọ ni oun rọ ẹgbọn iya rẹ lati gbe ọmọ naa lọ ile iwosan
BBC Panorama ṣe abẹwo si ẹgbẹ awọn ọdọ ni UCKG ni Brixton
Aworan safihan bí Pasitọ ṣe n awọn ọdọ sì isọri ọjọ orí wọn.
Ọdọ ọmọkùnrin to ba sọrọ ni ọmọ ọdun mẹrindinlogun nigba ti oun gba adura nla lọwọ Pasitọ.
"Ọlọrun mi, jẹ ki ina rẹ jo ẹmi esu kuro lara mi " Pasitọ gba adura.
Pasitọ di orí ọmọ naa mu, to si n gba adura pe ki ẹmi buruku jade laye rẹ.
BBC fi fọnran naa han Jahnine Davis, ajafẹtọ ọmọde.
O ni "Pẹlu nnkan to waye nípa iku Victoria Climbie ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin ati pẹlu fọnran yii, UCKG ni lati bere awọn ibeere kan lọwọ ara wọn.
"Ṣíṣe eto ilana jẹ nnkan, mimo juto jẹ nnkan mi, tí wọn ko ba mojuto ko ni itumọ
Ninu atẹjade UCKG, wọn ní "Adura nla jẹ nnkan ti a ma ṣe fun itusilẹ, ko ki n se ẹnikẹ́ni ti ko ba ti de ẹni ọdun mọkandinlogun.

BBC ba awọn olùjọsìn sọrọ
Pẹlu bi ẹka ile ijosin ṣe le ni ọgbọn ni ilẹ UK, ile UCKG ni oun yí ile awọn eeyan pada si daada
BBC ba awọn olùjọsìn ogoji to ti kuro ile ijọsin naa , àwọn mii tí kuro lọjọ tipẹ ti awọn mi si sẹsẹ kuro laipẹ.
Sharon darapọ mọ ẹka London Stratford nigba to wa ni ẹni ọdun mọkandinlogun.
O ni oun sọ fun Pasitọ awọn nnkan to n ṣe oun, o ni ko sọ fun lati ma gba imọran akọsẹmọsẹ fun Iranlọwọ.
"Mo ṣe adura nla, o de ibi kan n ko fẹ lọ mọ nitori ẹru n bami lati ati pe ẹmi wọn ma nka si ni gbogbo igba.
UCKG sọ fun BBC pe awọn ko lo ọgbọn lati awọn eeyan tabi lati gba lọwọ awọn eeyan.
Ile ijọsin ni pupọ awọn ololufẹ ile ijosin ni inu wọn dun pẹlu isẹ rere tí wọn n se.
Ṣugbọn pupọ awọn olùjọsìn to ti kuro ni ile ijọsin ni awọn ko le pada si ile ijọsin naa.















