Ọlọ́pàá àti èèyàn kan fara gbọta báwọn adigunjalè ṣe kọlu ọkùnrin kan tó lọ gbá owó ní Báńkì n‘Ibadan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Níṣe ni ọ̀rọ̀ di ẹni orí yọ ó dílé fún àwọn èèyàn ní agbègbè Secretariat ní Agodi, ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá nígbà àwọn adigunjalè ṣe ìkọlù sí ọkùnrin kan tó jẹ́ oníbàárà ilé ìfowópamọ́ kan.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo, Adewale Osifeso tó fi ìkéde náà síta sọ pé won kò tíì fìdí iye táwọn adigunjalè ọ̀hún gbà lọ́wọ́ ọkùnrin náà múlẹ̀.
Osifeso ṣàlàyé pé àwọn adigunjalè náà tọpinpin ọkùnrin náà tó ń gbé owó lọ sílé ìfowópamọ́ nínú ọkọ̀ Nissan Primera ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, tí wọ́n sì fi tipátipá gba owó náà lọ́wọ́ rẹ̀.
"Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo fi ń tó àwọn aráàlú létí pé ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè wàyè ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá, 2025 ní agbègbè Secretariat, Agodi tí wọ́n sì gba ọ̀bítíbitì owó tí a kò tíì fìdí iye rẹ̀ múlẹ̀."
"Kò sí ẹnikẹ́ni tó kú, ọlọ́pàá to fara gbọgbẹ́ ti ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn"
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà fi kun pé ọlọ́pàá kan tó gbìyànjú láti dá sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà fi ara gba ọta, tó sì ṣèṣe.
Ó ní ìwádìí fi hàn pé àwọn ọlọ́pàá kan tí wọ́n ń kọjá lásìkò tí ìkọlù àwọn adigunjalè náà ń wáyé gbìyànjú láti dá àwọn adigunjalè náà lẹ́kun, tí wọ́n sì dojú kọ ara wọn.
Ó sọ pé èyí ṣokùnfà bí ọlọ́pàá ṣe fara gba ọta, tó sì ṣèṣe gidi gan.
Odifeso fi kun pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ẹ̀mí rẹ̀ bọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé ọlọ́pàá to ṣèṣe náà ti ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn pẹ̀lú ààbò tó péye.
Bákan náà ló ró àwọn aráàlú tó bá ní ìmọ̀ lórí bí ọwọ́ ṣe le tẹ àwọn afurasí adigunjalè náà ní kíákíá láti kàn sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó bá wà ní agbègbè wọn.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè jẹ́ ohun tó sábà máa ń wáyé ní ìlú Ibadan. Ní oṣù Kẹfà ọdún yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè kan wáyé ní agbègbè Mokola níbi tí ọkùnrin kan ti ṣe ìkọlù sí oníṣòwò POS kan àti ọmọ rẹ̀.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nígbà náà pé oníṣòwò POS náà kò kú àmọ́ tí ìbọn bà á ní ẹ̀yìn mọ́ ibi itan.














