Ilé ẹjọ́ ṣàlàyé ìdí tó ṣe nira láti gbé Nnamdi Kanu kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Sokoto lọ sí Abuja

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Nnamdi Kanu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Adajọ James Omotosho, ti ile ẹjọ giga ilu Abuja to paṣẹ ẹwọn gbere fun olori ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu loṣu to kọja ti kọ ẹbẹ rẹ pe ki wọn gbe oun kuro ni ẹwọn ipinlẹ Sokoto lọ si ilu Abuja tabi ipinlẹ Nasarawa.

Kanu to pe fun gbigbe kuro naa ṣe eyi nipasẹ igbimọ oluranlọwọ nipa ọrọ ofin.

Ninu ipe naa ni wọn ti rọ ijọba apapọ Naijiria lati paṣẹ fun ajọ to n ri si ọgba ẹwọn, lati tete gbe Kanu kuro ni Sokoto lọ si ọgba ẹwọn Kuje l'Abuja, tabi ti Keffi, ni Nasarawa.

Bi eyi ko ba si ṣee ṣe, Nnamdi Kanu ni ki wọn gbe oun lọ si ọgba ẹwọn to ba wa lagbegbe kootu ti wọn ti dajọ foun l'Abuja.

Awọn bii Suleja tabi Keffi, koun le ni anfaani lati to iwe ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun toun fẹ pe lai si iṣoro.

O ni awọn awọn ẹbi ati awọn to le ran oun lọwọ lori ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun naa ko si nipinlẹ Sokoto, ilu Abuja ni wọn n gbe.

Bẹẹ irin ipinlẹ Sokoto si Abuja le ni kilomita ẹẹdẹgbẹrin (700km), eyi ti yoo jẹ iṣoro fun igbesẹ toun fẹ gbe lori ẹjọ naa.

Irù ẹ̀bẹ̀ yìí kò ṣeé gbà bí a kò bá gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀ -Adajọ Omotosho

Nigba to n kọ ẹbẹ Nnamdi Kanu lọjọ Aje ana, Adajọ James Omotosho, sọ pe ohun ti olori IPOB naa n fẹ ko le wa si imuṣẹ bi ijọba apapọ ko ba da si i, ki wọn si paṣẹ.

Adajọ Omotosho sọ pe bi olujẹjọ ṣe mọ nipa ohun to fẹ ṣe ni ijọba apapọ pẹlu ajọ to n ri si ọgba ẹwọn naa gbọdọ gbọ nipa ẹbẹ yii, ki wọn le fesi pada bi ofin ṣe sọ.

O ni nigba naa ni ẹbẹ rẹ too le jẹ itẹwọgba.

Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.

Tẹ o ba gbagbe, ogunjọ oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni kootu fidi ẹ mulẹ, pe Nnamdi Kanu jẹbi ẹsun onikoko meje to rọ mọ igbesunmọmi ti ijọba apapọ fi kan an.

Eyi naa si ni Adajọ James Omotosho fi ran an ni ẹwọn gbere.

Lẹyin rẹ ni wọn taari olori ẹgbẹ to n pe fun orilẹede Biafra naa lọ si ọgba ẹwọn ipinlẹ Sokoto, nitori aabo rẹ ti wọn ko le fọwọ sọya fun ni ọgba ẹwọn Kuje, nibi ti awọn ẹlẹwọn ti sa jade ri lawọn asiko kan.