Ẹ wo bí onírúurú ẹbí ṣe ń fi okòwò tata rán àwọn ọmọ wọn nílé ẹ̀kọ́, gbọ́ bùkátà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Asiko kan wa t'awọn tata alawọ ewe maa n pọ gan an lapa guusu Ariwa orilẹede Cameroon, pẹlu ayọ ati idunnu lawọn eeyan ẹkun naa maa fí n foju sọna si akoko naa.

Ọrọ aje gidi lo jẹ fun ọpọ eeyan níbẹ, wọn si maa n dọdẹ tata bi ẹni n dọdẹ ẹranko ninu igbo.

Ilu Bambui ti ko ju kilomita mẹẹdogun lọ sí Bamenda lẹkun guusu Ariwa Cameroon ni Mama Mbani Janet n gbe.

Ogbeni Joseph ọkọ Janet at'awọn ọmọ wọn l'ọkunrin l'obinrin n mura silẹ lati dọdẹ tata nírọ̀lẹ́.

Mama Janet sọ pe "a maa n foju sọna si akoko yìí lọdọọdun.

Oṣu ti a maa n mu saa ni oṣu ti a maa n ri tata yii mu.

Eledua fi ọpọlọpọ ọmọ jinki mi.

Gbogbo wọn lo si ti wa nile ẹkọ, iṣẹ ọtika ti mo n ṣe ko to wa jẹ mọ.

Amọ, mo mọ pe nnkan maa n yatọ daadaa fun wa laarin oṣu Kẹwàá ọdún si oṣu Kejìlá," Arabinrin Janet lo sọ bẹẹ.

Ṣiṣe odẹ tata ti wọn maa n pe ni Mungwin ni ede Cameroon jẹ nnkan to ti di aṣa nilẹ naa, o si jẹ ọrọ aje fun ọpọ eeyan níbẹ.

Wọn maa n máwọn tata yii ni irọlẹ, wọn si maa ṣe aayan rẹ.

Lẹyìn naa ni won maa n ta a yala ni gbígbẹ tàbí ni tutu.

Orisiirisii ohun elo bíi paanu òrùlé ati goro ni wọn maa n lo lati mu tata

Fún àwọn eeyan bíi Mama Janet, okowo tata yii lo maa n sọ bo ya awọn ọmọ rẹ yoo pada sile ẹkọ, tabi wọn o le san gbese ti ẹbí jẹ.

Bi wọn ba se ri tata yii mu si ni yoo tun sọ bo ya ẹbi mama yoo le jẹ ounjẹ gidi lasiko ọdún Keresimesi.

Lẹyìn ile mama Janet ati ọkọ rẹ Joseph ni igbaradi lati lọ soko ọdẹ tata alawọ ewe ti maa n waye.

Orisiirisii ohun elo bíi paanu òrùlé ati goro ni wọn maa n lo lati mu awọn tata yii.

Ọpọ ọmọbibi Cameroon ni wọn gbọju mọ awọn ọna ti wọn maa n gba lati mu tata yìí.

Lati bii ọmọ ọdun mẹwàá si mẹẹdogun lawọn ọmọde ti maa n lo paanu orule ati goro lati fi mu tata.

Ni igberiko bii Bambili ti mama Janet n gbe ti wọn ti ni ipenija ina mọnamọna, Joseph àti iyawo rẹ ti ra ẹrọ amunawa lati le maa fi riran lalẹ.

Mama Janet sọ pé "ni gbogbo igba ni a maa n wa nibi lasiko t'awọn tata ba ti bẹrẹ sii jabọ.

Emi at'awọn ọmọ mi maa n ri pe awọn tata yii ko sa mọ wa lọwọ."

Àwọn tata yii maa n fo lọ sibi ina to wa ni titan sílẹ.

Awọn ọmọde si maa n gbe ike lọ síbẹ lati ko wọn.

Awọn to máa ń ṣọdẹ tata yii maa n ṣee titi di oru ni.

Idunnu maa n ṣubu layọ fun ẹbi mama Janet lalaalẹ torí wọn mọ iye tí wọ́n maa ri nibi tata ti wọn ti mú.

Asiko ọja tita

Lati bii ago mẹfa lawọn eeyan maa ti n de oja laarọ láti ta tata ti wọn ba mú.

Owo gọbọi ni wọn maa n ta tata tutu lasiko rẹ.

Ọpọ awọn alaratunta lo maa n wa lati ọna jinjin lati ra tata.

"Mo maa n ta garawa tata tutu kan ni bíi 8,000 francs.

Mo si maa n ta to garawa marun un lojumọ.

Owo tata yii maa n ṣè'rànwọ́ fawọn ẹbi ti wọn kii ṣe oníṣẹ ìjọba.

Kìí ṣe gbogbo tata ti wọn ba mu yii naa ni wọn maa n ta.

Awọn ẹbi mii maa n jẹ àwọn tata ti wọn ba mu nigba mii.

Nigba mii ẹwẹ, wọn maa n ṣeto tata yii ti won yoo si sa a loorun ti yoo fi gbẹ.

Lẹyìn náà ni wọ́n yoo ko o pamọ lati ta to ba ya.

Koda, wọn tun máa n ko tata ranṣẹ sílẹ okeere fun tita nigba mii.

Ọrọ aje to n ṣeranwọ

Olugbe ilu Bambui mii, mama Acha Mary sọ bii akoko ti wọn maa n ri tata mu ti ṣe pàtàkì tó.

"Mungwin ti ran mi lọwọ láti san owo ile ẹkọ awọn ọmọ mi.

Asiko yii jẹ asiko manigbagbe fun mi."

Ọrọ Arabinrin Mary fi idi rẹ múlẹ síi bí okowo tata ṣe n ran ọpọ ẹbi lọwọ.

Joseph ati aya rẹ, Janet naa tun jẹri si ọrọ ọhun

"Okowo tata yii ni a fi n ran awọn ọmọ wa lọ ile ẹkọ."

Okowo tata yii lo n ran ọpọ ẹbi ti oṣi ati iṣẹ ko ba maa ba finra lọwọ.

Mama Janet ni iyanu ni okowo tata jẹ fun ẹbi oun torí ohun lawọn fi n gbọ ọpọ bukata.

Bi asiko tata ọdún yii ṣe n kogba wọle diẹ diẹ, awọn ẹbi Joseph, Arabinrin Mary ati mama Janet ti bẹrẹ sii foju sọna si igba ti akoko rẹ yoo tun de lọdun to n bọ.