Èébú àti èpè tí ẹ fi ń ránṣẹ́ kò tu irun kankan lára mi, mò ń bọ̀ wá bá ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dín àkàrà lójú pópó torí mi, a dìjọ máa jẹ àkàrà náà ni - Makinde

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti ní òun máa jíròrò pẹ̀lú àwọn olùgbé agbègbè Ologuneru ní pilú Ibadan èyí tí àkànṣe iṣẹ́ òpópónà Circular Road ṣe ìdíwọ́ fún ibùgbé wọn.

Makinde ní gẹ́gẹ́ bí ìlérí òun láti ri pé gbogbo èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo ló jẹ mùnkúndùn ìjọba àwaarawa, ó ní òun máa ṣe àbẹ̀wò sí òpópónà náà, bá aráàlú sọ̀rọ̀, tí òun yóò sì ri dájú pé gbogbo àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ sí owó gbà mábinú ni àwọn máa fún.

Bákan náà ló ní àwọn máa wòye sí pípèsè ààyè míì fáwọn tí òpópónà náà ṣe àkóbá fún ibùgbé wọn.

Gómìnà Makinde ló sọ èyí lásìkò tó gbé àbá ìsúná ọdún 2026 síwájú ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kọkànlá, 2025.

Ó ní gbogbo èébú àti èpè táwọn èèyàn kan fi ń ránṣẹ́ sí òun lórí ilẹ̀ náà kò tu irun kankan lára òun nítorí òun gbà pé lára nǹkan tí ẹni tó bá ti jẹ́ olórí máa ń gbà ni.

Ó wòye pé kìí ṣe ìṣèjọba òun ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe òpópónà náà bíkòṣe ìjọba tó gbésẹ̀ tí wọ́n ti gba ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mítà ilẹ̀ ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa pàtàkì ṣíṣe òpópónà Circular Road náà, ó ní ó jẹ́ ojúnà láti mú ìdàgbàsókè bá ìpínlẹ̀ Oyo ni, tó sì ṣèkìlọ̀ fáwọn olóṣèlú tó fẹ́ máa lo ọ̀nà ọ̀hún láti fi dá wàhálà sílẹ̀ láàárín ìlú.

Ó fi kun pé òun máa ṣe àrídájú rẹ̀ láti ri pé òun ṣe déédéé, kí ìjọba òun sì má fi sí apá kan ju èkejì lọ.

"Mo máa mú ìlérí mi ṣẹ láti tẹ́tí sí aráàlú àti láti ṣe gbogbo ohun tó tọ́ nípa fífún àwọn èèyàn ní owó gbà mábinú ní àfikún sí kíkó wọn ló sí agbègbè míì."

"Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dín àkàrà nítorí mi, mó ń bọ̀ wá sí àdúgbò Ologuneru lọ́la, a jọ máa jẹ àkàrà náà ni."

Makinde tún wòye pé yàtọ̀ sí òpópónà, ìpínlẹ̀ Oyo nílò ìdásílẹ̀ àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá àtàwọn awakùsà tó máa wá àwọn ohun àlùmọ́nì ilẹ̀ tí Ọlọ́run fi ta ìpínlẹ̀ náà lọ́rẹ lójúnà àti gbé ìpínlẹ̀ Oyo dé èbúté ògo.

Báwo ni ìjọba Oyo ṣe fẹ́ ná àbá ìsúná 2026?

Ṣaaju ni Gomina Makinde ti gbe aba isuna ₦891,985,074,480.27 kalẹ niwaju awọn asofin ipinlẹ naa fun ijiroro ati fifi ontẹ lu fun ọdun luu fun ti ọdun 2026.

Abadofin eto isuna ti Gomina pe ni "isuna fun gbigbooro eto ọrọ-aje" ni wọn ti fẹ na 502.8bn fun eto idagbasoke nigba ti ẹka eto ẹkọ yoo gba 155.2bn.

Eto ilera ni tirẹ yoo na ijọba to N70.8bn nigba ti ẹka eto ọgbin si gbe 19.9bn.

Gomina salaye wipe aba isuna yii yoo ran ipinlẹ Ọyọ lọwọ lati mu eto ọrọ aje wọn da musemuse.

O safihan awọn isẹ ribiribi ti ipinlẹ Oyo n se, bii igbesoke papakọ ofurufu Ladoke Akintọla ti Ibadan, Ọna Ibadan olobiripo Rashidi Ladoja ati awọn akanse isẹ miran ti yoo jẹ ki ipinlẹ naa dagbasoke si.

O tunbọ salaye wi pe ipinlẹ naa yo se ayẹyẹ aadọta ọdun ninu oṣu Keji ọdun 2026 ti o si ṣe afikun wi pe ayẹyẹ naa wa fun koriya awọn ọmọ ipinlẹ Ọyọ.

Nigba to n sọrọ lori ipenija aabo to n ba orilẹ-ede Naijiria finra lasiko yii, Gomina fidi ẹ mulẹ pe Ipinlẹ Ọyọ ti se agbekale eto aabo to yanranti ni gbogbo ilu kaakiri paapaa julọ

O salaye wipe awọn ara ilu mọ ohun ti o tọ ni ilana ofin, ti o si salaye wi pe awọn ti wọn n gbin ọtẹ si aarin ilu o le ri ibo yi ni ọdun 2027.

Ninu ọrọ rẹ, Olori ile-igbimọ asofin ipinlẹ Ọyọ, Adeseun Ogundoyin kan saara si gomina fun isẹ ribiribi ti o se pẹlu eto isuna ti wọn buwọlu ni ọdun 2025.

O ṣe afikun pe abadofin yii jẹ esi ijiroro ti ijọba ti se pẹlu awọn ti ọrọ kan ni ẹkun meje ti ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si ti gbọ erongba wọn.

O tunbọ salaye wi pe ile-igbimọ asofin kẹwaa naa ko ni kẹti lati maa ṣe ojuṣe wọn, ti awọn yoo si ri wi pe awọn sisẹ pẹlu Gomina lati ri wipe gbogbo owo ti eto isuna la kalẹ lọ bo se yẹ.

Lara awọn to peju sibi ipejọ naa ni Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Abimbọla Ọwọade, Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladọja, Olugbọn tilu Orile-Igbọn, Ọba Francis Alao, Asẹyin ti ilu Isẹyin, Asoju Soun Ilẹ Ogbomọsọ ati awọn ladelade miran.