Ìyá àtí ọmọ rí ẹ̀wọn he lórí ẹ̀sùn pé wọ́n sẹkúpa ìbátan ọkọ rẹ̀

Aworan

Ileẹjọ Magisreti ni ilu Makurdi ti ran arabinrin Rosaline Iyorshe ati ọmọ rẹ Tertsea ni ẹwọn lori ẹsun pe wọn ba ibakan ọkọ rẹ.

Ẹsun ti wọn fi kan ibatan ọkọ rẹ ti wọn ba ni pe o ji ẹran ni Ọjọ kọkandinlọgbọn, Oṣu Kini, ọdun 2023.

Bio tilẹ jẹpe agbẹjọro naa ko gba beeli wọn wọn amọ o sun igbẹjọ naa siwaju di Ọjọ Kẹjọ, Osu Keji, ọdun 2023.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye...

Saaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ẹsun ipaniyan kan Charity, ti o si ni ẹṣun naa tako ẹka iwe ofin Section 97 ati 222 ti ipinlẹ 2004.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn gba ipe pajawiri kan pe Charity ati ọmọ rẹ na Fanen to jẹ ibatan ọkọ rẹ to n gbe pẹlu wọn.

Agbẹjọrọ naa ṣalaye pe Charity ni oun na Fanen nitori o lọ ji ẹran ninu ikoko ọbẹ oun.

Lẹyin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn gba iroyin pe Fanen daku gbọnragandan nitori lilu ti wọn naa, ti wọn si gbe digba digba lọ si ileewosan.

Amọ wọn ni Fanen gbe ẹmi mi lasiko to n gba itọju nile iwosan.