You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọwọ́ NDLEA tẹ afurasí afọ́jú ọkùnrin mẹ́ta tó ń ṣe káràkátà egbògi olóró
Ajọ to n gbe ogun ti lilo egbogi oloro lorilẹede Naijiria ni o le ni milọnu mẹrinla egbogi oloro Tramadol ati egbogi oloro oni mimu Codeine toto bilọnu mẹtala naira ni awọn ri gba lọwọ afurasi ni agbegbe Amuwo Odofin, Idumota ati ni paapa ofurufu Muritala Muhammed to wa ni agbegbe Ikeja nipinlẹ Eko.
Lara awọn ti ọwọ tẹ ni awọn afọju ọkunrin mẹta kan ti wọn n ṣe karakata egbogi oloro lati ipinlẹ Eko lọ si ipinlẹ Eko.
Ninu ọrọ ti ajọ naa fi lede fun awọn akọroyin, eyi ti agbẹnusọ ajọ naa, Femi Babafemi buwọlu salaye ọkan lara awọn afọju naa fẹsẹ.
“Ọwọ tẹ Adamu Hassan, ẹni Ogoji ọdun ni ọna marosẹ Gwagwalada niluu Abuja lasiko to n lọ ilu Kano lati ipinlẹ Eko lọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kẹwaa ti egbogi si wa ninu apo baagi rẹ to gbe rin irinajo.
“Iwadii fihan pe o mọ ohun to wa ninu apo naa.
“Nigba ti a tẹ siwaju ninu iwadii ni a tun ri afọju miiran ti orukọ rẹ n jẹ Bello Abubakar, ẹni ọdun marunlaadọta.
"Ninu ọrọ rẹ, o ni oun ni iyawo ati ọmọ marun un, to si ti n gbe ilu Eko fun ọgbọn ọdun sugbọn o bẹrẹ okowo egbogi oloro ni nnkan bi ọdun marun un sẹyin.”
"Bakan ni ọwọ tun tẹ ọrẹ Bello Abubakar ti oun naa jẹ afọju, to si jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgọta, ti orukọ rẹ n jẹ Muktar Abubakar.
Gẹgẹ bi NDLEA ṣe gbe jade, Muktar Abubakar ni oun ni iyawo mẹta, to si bi ọmọ mẹrinla, ti oun ati ikeji rẹ Bello Abubakar si jọ da okowo egbogi oloro silẹ.
Afurasi kẹta, Akilu Amadu, ẹni ọdun mẹdọgbọn, ti oun naa jẹ afọju naa dowo pọ pẹlu awọn Abubakar, to si jẹ pe oun lo fi egbogi oloro ran Adamu ti ọwọ tẹ loju ọna rẹ siluu Kano.
Ọkan lara awọn afurasi , Mallam Aminu ti fẹsẹ gẹgẹ bi NDLEA se gbe iroyin naa jade.