Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lẹ́dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ láti pa olùkọ́ fásitì

Ajọ ọlọpaa nipinlẹ Niger, laarin gbungbun ariwa orilẹ-ede Naijiria lo ti fi panpẹ ofin mu ọdọmọdebirin kan, ọmọ ọdun mẹrinla kan pe o ṣekupa Ọmọwe Funmilayo Adefolalu.

Iṣẹlẹ naa lo waye ni ọjọ kejidinlogun oṣu kẹwa ọdun 2023.

Ọmọwe Funmilayo to jẹ olukọ ni fasiti imọ ẹrọ to wa nilu Minna lo gba ọmọ naa bii ọmọ ọdọ fun ọsẹ mẹta ki o to lee lọ.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe wi, Funmilayo lo wa ninu ile rẹ lakoko ti ọmọbirin naa na wọle tọọ wa, to si fi apoti gbaa lori ko to di wi pe wọn gun pa.

“Nigba taa de ibẹ, ara oloogbe naa la ba nilẹ pẹlu ọbẹ meji ti ẹjẹ wa lara rẹ.

A gbe ara naa lọ ileewosan IBB ni Minna, nibi tawọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe ẹmi ti bọ lara rẹ.”

Agbẹnusọ ajọ ọlọpaa nipinlẹ Niger, DSP Wasiu Abiodun, wi pe ọrọ ti wọn gbọ lẹnu awọn alabagbe ati ọrẹ oloogbe naa lawọn fi ri ọmọdebinrin naa mu.

“Awọn ọmọ kilaasi rẹ meji to fẹsun kan pe wọn ran oun lọwọ ti sa lọ amọ a n sa gbogbo ipa wa lati ri wọn mu.”

Fásitì n dárò akíkanjú olùkọ́

Fasiti ti ọmọwe Funmilayo ti n ṣiṣẹ lo ni awọn n ṣedaro akikanju olukọ naa to jẹ ọjọgbọn ni ẹka ẹkọ Biochemistry.

Atẹjade kan latọwọ Arabirin Lydia Legbo to jẹ adari ẹka ipolongo ati iroyin ni fasiti naa fihan pe oloogbe naa lo dara pọ mọ wọn bii oluranlọwọ olukọ lọdun 2005.

Ọmọ bibi ilu Ṣaki nipinlẹ Oyo, ni iwọ-oorun-guusu orilẹ-ede Nigeria ni olukọ to papo da naa.

“Ohun ibanujẹ ni iṣẹlẹ yii jẹ fun gbogbo wa ninu ọgba yii tori pe akikanju to ni itara iṣẹ ni oloogbe naa.

Adura wa ni ki Olorun tẹẹ si afẹfẹ rere ki awọn agbofinro si ni okun lati letẹsiwaju ninu iwadi wọn.”

Kí ló kàn fún ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tí ọwọ́ tẹ̀?

Agbẹjọro Wada Wada to je oluranlọwọ aarẹ ni ọfiisi agbefọba agba ni Naijiria ṣalaye fun ikọ BBC pe ọmọdebirin naa yoo koju igbẹjọ nile ẹjọ bii agbalagba.

“Igbẹjọ yoo waye bo ṣe yẹ nile ẹjọ giga amọ idajọ ko nii le waye titi ọmọ naa yoo fi pe ọdun mejidinlogun.

Lẹyin igbẹjọ, wọn yoo fi ọmọ naa pamọ si ile ipamọ awọn ọmọde to wa ninu ọgba ẹwọn titi di akoko ti yoo pe ọdun mejidinlogun ti idajọ yoo fi waye.

Amọ ko si iyatọ kan laarin igbẹjọ rẹ ati ti agablagba” ni Wada wi.