You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Fubara rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Rivers lórí làásìgbò òṣèlú tó wáyé láàárín òun àti Wike
Gomina ipinlẹ Rivers, Siminalayi Fubara, lo ti rawọ ẹbẹ si gbogbo ọmọ ipinlẹ naa lori ohun to juwe bii ede-aiyede to bani lọkan jẹ to waye nipinlẹ naa.
Bakan naa ni gomina ọun dupẹ lọwọ aarẹ Bola Tinubu, awọn agba ipinlẹ Rivers, atawọn gomina akẹgbẹ rẹ fun ipa ti wọn ko lati pana aawọ naa.
Ninu atẹjade kan ti gomina naa buwọlu funra rẹ to pe akori rẹ ni “alaafia ko lẹgbẹ”, Fubara wi pe gbogbo igbesẹ oun lati igba ti ile aṣofin ipinlẹ naa ti jona, ede aiyede to waye nile aṣofin naa ati abẹwo oun sibẹ lo da lori ki alaafia le jọba nipinlẹ naa.
Gomina ọun wi pe gẹgẹ bi ẹni to nifẹ alaafia, itẹsiwaju ipinlẹ Rivers lo jẹ oun logun ati pe ko si ohun to le ju lati ṣe ki eyi o lee waye.
Fubara wi pe “ojuṣe gomina tẹlẹ ri to tun jẹ minisita fun ilu Abuja, Nyesom Wike, ati emi naa ni lati lo ipo ati ọla wa fun agbega, itẹsiwaju, aabo to peye ati igbaye-gbadun awọn eeyan wa.
Nitori idi eyi, a ko gbọdọ gba ki ohunkohun o dena ilakaka wa lati mu agbega ba awọn eeyan wa.
Ni temi, mo ṣetan lati tẹwọ gba gbogbo igbesẹ ti aarẹ Tinubu, awọn eekan ilu jakejado Naijiria to fi mọ awọ gomina akẹgbẹ mi atawọn agbaagba n gbe lati mu ki alaafia o jọba.
Mo fi da gbogbo eeyan ati ọdọ ipinlẹ Rivers loju pe alaafia yoo jọba, a yoo si tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ pọ fun alaafia, aabo, itẹsiwaju ati idagbasoke ipinlẹ wa.
Gẹgẹ bii gomina yin, mo tọrọ aforijin lọwọ gbogbo ẹyin eyan daadaa nipinlẹ Rivers fun ede-aiyede to bani lọkan jẹ eyi to n waye lati ọjọ diẹ sẹyin, mo si dupẹ fun atilẹyin, ifẹ ati adura yin.”