Iléẹjọ́ gba Rochas Okorocha láàyè láti lọ sí òkè òkun fún ítọ́jú ara

Ileẹjọ giga ti ilu Abuja ti fun gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, Rochas Okorocha ni anfaani lati rin irinajo lọ si oke okun fun eto ilera ara rẹ.

Agbẹjọrọ agba Inyang Ekwo to pa aṣẹ naa ni ileẹjọ tun paṣẹ ki wọn da iwe irina rẹ pada fun un ki o le lọ gba iwosan to nilo.

Eyi ko ṣẹyin bi agbẹjọro rẹ, Ola Olanipekun ṣe sọ fun ile ẹjọ pe Okorocha ni idojukọ aisan ni agọ ara rẹ lati igba diẹ.

O ni o da oun loju pe Okorocha ko ni doju ofin bolẹ, pe yoo pada si Naijiria lati wa jẹjọ rẹ ni kete ti ara rẹ ba ti mokun.

Amọ, Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC tako igbeṣẹ naa amọ aṣẹ ile ẹjọ bori lori, lasiko igbẹjọ naa.

Ileẹjọ fikun un pe kete lẹyin ọjọ mẹta to ba pada de si Naijiria ni ko fi iwe irinna rẹ ranṣẹ si ileẹjọ.

Adajọ ọhun tun fikun un pe oun yoo fi aṣẹ ‘mo n wa ọ’’ sita fun Okorocha to ba kọ lati tẹle aṣẹ ileẹjọ.

Bakan naa lo sun igbẹjọ rẹ di Ọjọ Keje, Oṣu Kọkanla lati tẹsiwaju lori ẹsun iwa ajẹbanu ati lilu owo ilu ni ponpo to le ni biliọnu mẹta naira, ti ijọba apapọ Naijiria fi kan an.