You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Paul Biya, ààrẹ Cameroon tó ti wà lórí oyè láti ọdún 1982 tún fẹ́ dupò fún sáà kẹjọ
Aarẹ orilẹede Cameroon, to jẹ ẹni ọdun mejilelaadọrun ti kede pe oun yoo tun du ipo Aarẹ fun saa kẹjọ lẹyin to ti lo ọdun mẹtalelogoji lori oye.
Paul Biya lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan loju opo X rẹ nibi to ti ṣeleri lati tan iṣoro ti orilẹede naa n koju.
Lati igba to ti gori aleefa lọdun 1982, Biya lo n bori gbogbo ibo aarẹ ti wọn n di ni Cameroon lati ọdun naa.
To ba bori ibo to n bọ yii, yoo din diẹ lẹni ọgọrun ọdun ki saa rẹ to pari.
O ni igbese oun lati du ipo ipo fun igba kẹjọ ko ṣẹyin bi awọn ọmọ orilẹede naa nile ati lokeere ṣe n kesi oun lati dije fun ipo ọhun.
Ọpọ araalu lati ẹyin wa lo ti bu ẹnu atẹ lu ijọba ọkunrin naa latari oniruru ẹsun iwa lilu owo ilu ni ponpo ti wọn fi kan an.
Wọn tun ni ko mojuto eto aabo ati pe agbara ilera rẹ ko gbe iṣẹ Aarẹ mọ.
Lati bii ọsẹ mẹfa sẹyin ni awọn eeyan ko ri ni gbangba mọ eyii to mu ki wọn maa sọ pe o n ṣaisan, koda awọn mii n sọ pe niṣẹ lo ti dagbere faye.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ orilẹede naa n reti pe yoo kede pe oun yoo dije, amọ ko ṣe bẹẹ titi to fi kede loju opo X rẹ.
Ọpọ eeyan ni Cameroon ati kaakiri agbaye lo ti n ke si Biya ko fi ipo silẹ lẹyin ọpọ ọdun ki awọn mii le gbajọba.
Laipẹ yii ni awọn alabaaṣisẹ rẹ kan ti wọn maa n ba ri ibo to pọ ni ariwa orilẹede naa pinya pẹlu rẹ.
Awọn oloṣelu ọhun, Issa Tchiroma Bakary ati olootu ijọba, Bello Bouba Maigari sọ pe awọn naa fẹ dije du ipo Aarẹ.
Tchiroma sọ loṣu to kọja pe ijọba Biya ti ja ireti araalu kulẹ ati pe oun yo darapọ mọ ẹgbẹ alatako.
Lara awọn alatako mii to tun ti kede pe awọn yoo dije ni Maurice Kamto, to gbe ipo keji ninu ibo ọdun 2018, atawọn mii bii Joshua Osih, Akere Muna, ati Cabral Libii.
Amọ ṣa, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Biya, People's Democratic Movement atawọn alatilẹyin rẹ ti sọ pe oun gan an ni awọn n fẹ ko du ipo naa, ko si ni alatako kankan ninu ẹgbẹ oṣelu ọhun.
Ọdun 2008 ni Biya fopin si saa fun aarẹ to si fun ara rẹ lanfaani lati maa dije titi lai.
Ninu ifọrọwerọ pelu awọn araalu kan, wọn ni Biya gan an ni awọn fọwọsi ko di aarẹ, bẹẹ lawọn mii sọ pe akoko rẹ ti kọja, nitori naa ko lọ fẹyinti.
Lọwọ yii, ọkunrin ọhun ni aarẹ orilẹede to dagba julọ ni gbogbo agbaye.