You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo orílẹ́èdè mẹ́wàá tí o lè lọ láti Naijiria láì gba físà
Irinajo si orilẹede ilẹ okeere maa n kọ ọpọ ọmọ Naijiria lominu, bo tilẹ jẹ pe nnkan to yẹ ko jẹ idunnu ni.
Ọrọ ati ri fisa gba lọ si orilẹede ilẹ okeere lo maa n ṣaba kọ awọn ọmo Naijiria lominu.
Lọpọ igba lawọn eeyan maa n to niwaju ọfiisi olu ileeṣẹ ijọba ilẹ okeere ni Naijiria tori wọn fẹ gba fisa.
Amọ, gbogbo wahala yii ko sọ pe ki wọn tun ri fisa ọhun gba rinrin ajo lọ si ilẹ okeere ti wọn fẹ lọ.
Ṣugbọn iroyin ayọ ni pe kii ṣe gbogbo orilẹede ilẹ okeere lo nilo ki eeyan gba fisa lati Naijiria ki eeyan to le rinrin ajo lọ sibẹ.
Awọn orilẹede ilẹ okeere kan wa ti ko nilo ki eeyan gba fisa lati Naijiria ki ẹni naa to le rinrin ajo lọ sibẹ.
Wọnyii ni orilẹede mẹwaa ti o le lọ pẹlu iwe irinna rẹ lati Naijiria lai gba fisa:
Rwanda
Orilẹede Rwanda jẹ ọkan lara awọn orilẹede ti eeyan le lọ pẹlu iwe irinna Naijiria lai gba fisa.
Nigba ti eeyan ba rinrin ajo de Rwanda tan ni ijọba orilẹede naa maa n ṣe fisa fawọn alejo lati Naijiria.
Rwanda jẹ orilẹede kan to mọ toni toni nilẹ Afirika ti idagbasoke si wa nibẹ.
Ọgba ẹranko to dara wa lara awọn ibi ti eeyan le ṣabẹwo si ni Rwanda, ati pe awọn eeyan orilẹede naa tun ko alejo mọra.
Ghana
Gẹgẹ bii ọmọ Naijiria, o ko nilo fisa lati rinrin ajo lọ si orilẹede Ghana.
Ko si nnkan mii ti o nilo ju iwe irinna rẹ tabi kaadi idanimọ lọ.
Wakati mejila ni ọkọ maa n lo lati Naijiria si Ghana, ọpọ awọn nnkan afijọ lo wa laarin Naijiria ati Ghana.
Oniruuru orin bi Afro, faaji leti okun to fi mọ awọn ọja ti eeyan ti le ra nnkan lo wa niluu Accra ti i ṣe olu ilu Ghana.
Seychelles
Oṣu mẹta gbako ni eeyan fi le wa ni orilẹede Seychelles lai gba fisa.
Eeyan le ṣabẹwo si orilẹede Sychelles ti ẹni naa ba fẹran lati maa fomi okun ṣere.
Oriṣiiriṣii erekusu to rẹwa ti eeyan le rinrin ajo afẹ lọ lo wa lorilẹede Seychelles.
Seychelles dara fawọn lọko laya to ṣẹsẹ ṣe igbeyawo tan lati rinrin ajo afẹ lọ, bakan naa ni eeyan le da lọ sibẹ fun irinajo igbafẹ.
Barbados
Njẹ o mọ pe eeyan le wa ni Barbabos fun oṣu mẹfa lai gba fisa?
Ounjẹ wọn dara ni Barbados, orin ti eeyan le fi ṣe faaji naa ko gbẹyin.
Awọn eeyan orilẹede yii tun ni aṣa to ko eeyan mọra.
Barbados wa lara awọn orilẹede erekusu ti eto abo to peye wa nibẹ.
Maldives
Nigba ti eeyan ba rinrin ajo de orilẹede Maldives tan ni ijọba ilẹ naa maa n ṣe fisa fawọn alejo.
Yala lọkọ laya niyin ni abi iwọ kan fẹ da rinrin ajo afẹ lọ si Maldives, idaniloju wa pe igbadun wa ni orilẹede ọhun fawọn arinrin-ajo.
Omi okun nibi tawọn eeyan ti le ṣere, bakan naa ni awọn ile itura wa kaakiri lorilẹede ọhun.
Singapore
Lori ẹrọ kọmputa lawọn alejo ti maa n ṣeto fisa wọn ti wọn ba de orilẹede Singapore.
Singapore wa lara awọn orilẹede ti imọtoto wa nibẹ.
Bakan naa ni orilẹede naa tun fọkan balẹ fawọn obinrin lati gbe.
Iwọ ti o ba fẹran lati maa ra nnkan lawọn ile itaja igbalode, Singapore ni iru rẹ daadaa.
Kenya
O ko nilo lati gba fisa ki o to le rinrin ajo lọ si orilẹede Kenya.
Awọn eeyan Kenya gboge, ẹka imọ ẹrọ ati iṣẹ ọna wa lara nnkan tawọn eeyan maa n sọ nipa rẹ ni Kenya.
Bakan naa ni afijọ wa laarin aṣa awọn eeyan Kenya ati ti Naijiria, eyi ti yoo jẹ ki ara eeyan le tete mọle nibẹ.
Cape Verde
Ọmọ Naijiria le wa ni orilẹede Cape Verde fun oṣu mẹta gbako lai gba fisa.
Orilẹede ti ko si jagidijagan lẹkun iwọ oorun Afirika ni Cape Verde jẹ.
Ti iwọ ba n wa ibi ti o ti le gbọ orin gidi tabi ibi ti o ti le ri ounjẹ gidi jẹ ati omi okun fi ṣere, Cape Verde ni o ti le ri awọn nnkan yii.
Dominica
Orilẹede Dominica tun ni orilẹede mii ti eeyan le lọ lati Naijiria lai nilo fisa.
Oniruuru omi to da lati oke silẹ, igbo atawọn odo lo mu Dominica rẹwa.
Orilẹede Dominica dara fawọn to ba n wa ibi ti ko si ariwo lati rinrin ajo afẹ lọ.
Fiji
Ọmọ Naijiria le wa ni orilẹede Fiji fun oṣu mẹrin lai nilo fisa.
Yatọ si pe ko si ariwo lorilẹede Fiji, oriṣiiriṣii erekusu okun to rẹwa lo wa nibẹ.
Fiji jẹ ibi ti awọn eeyan ti ko fẹ ariwo le rinrin ajo afẹ lọ.