You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gbogbo nnkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìrìnàjò Muhammadu Buhari láti kékeré títí tó fi kú
Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Muhammadu Buhari, to ku lẹni ọdun mejilelọgọrin, ti figba kan ri jẹ olori ologun orilẹede Naijiria ki o to di aarẹ alagbada lẹyin to dupo aarẹ ninu idibo gbogbogbo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.
Amọ, ọpọ ọmọ Naijiria ni ko gbagbọ wi pe Buhari mu awọn ileri to ṣe ṣẹ lasiko to wa nipo aarẹ.
Bi Buhari ṣe maa n ṣe yatọ sawọn olosẹlu yooku, o maa n saba duro lori ọwọ rẹ ni nigba aye rẹ.
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo mọ ọn gẹgẹ bi olootọ eeyan, eyi to ṣọwọn laarin awọn oloṣelu Naijiria.
Lẹyin to dupo aarẹ fun igba mẹta ọtọọtọ ti ko wọle, Buhari pada wọle ibo aarẹ ọdun 2015, o si di oludije sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu alatako akọkọ ti yoo la aarẹ to wa lori oye mọlẹ ninu eto idibo ni Naijiria.
Ko tan sibẹ o, Buhari tun wọle fun saa keji gẹgẹ bii aarẹ ọrilẹede Naijiria lọdun 2019.
Ilumọọka ni Buhari i ṣe tipẹ tipẹ laarin awọn mẹkunnu (ti wọn maa n pe ni ''talakawa'' lede Hausa) lapa ariwa Naijiria.
Amọ, agbarijọpọ ẹgbẹ oṣelu alatako lo ṣatilẹyin fun un lasiko ipolongo ibo aarẹ ọdun 2015.
Ero ọpọ eeyan to ṣatilẹyin fun Buhari nigba naa ni pe yoo lo iriri rẹ gẹgẹ bii olori ologun kogberegbe Naijiria tẹlẹ ri lati wa ojutuu si iṣoro awọn agbesunmọmi alakatakiti ẹsin islam to n ṣọṣẹ lapa ariwa Naijiria.
Buhari tun ṣeleri lati gbogun ti iwa ajẹbanu to gogo ni ijọba, bakan naa lo tun ṣeleri lati pese iṣẹ fawọn ọdọ ti ko ri iṣẹ ṣe.
Amọ, asiko rẹ gẹgẹ bii aarẹ Naijiria ni owo epo rọbi ja lulẹ lagbaaye, asiko yii naa si ni eto ọrọ aje Naijiria dẹnu kọlẹ julọ fun ọpọlọpọ ọdun.
Buhari tun ṣeleri lati ṣẹgun ẹgbẹ alakatakiti ẹsin ati agbesunmọmi Boko Haram, ṣugbọn Boko Haram si n ṣọṣẹ titi di oni ni Naijiria.
Koda, ẹka Boko Haram kan ti n ṣiṣẹ pọ bayii pẹlu ẹgbẹ agbesunmọmi ISS.
Ija laarin awọn agbẹ atawọn Fulani darandaran peleke sii lẹkun aaringbungbun Naijiria lasiko Buhari.
Ọpọ lo fẹsun kan Buhari toun naa jẹ ẹya Fulani wi pe o fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ ija laarin awọn agbẹ atawọn Fulani darandaran.
Eto abo mẹhẹ debi wi pe awọn agbesunmọmi ji ọpọ akẹkọọ ile ẹkọ girama gbe lọ lẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria.
Lasiko Buhari naa ni wọn fẹsun titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ kan awọn ologun – fun apẹẹrẹ, bii yiyin ibọn fawọn oluwọde tako awọn ọlọpaa to n huwa ipa si araalu (iwọde EndSARS) ni Lekki tollgate loṣu Kẹwaa ọdun 2020 niluu Eko.
Ta ni Muhammadu Buhari?
Ni oṣu Kejila, ọdun 1942 ni wọn bi Buhari ni ilu Daura, ipinlẹ Katsina, ẹkun ariwa Naijiria to paala pẹlu orilẹ ede Niger. Lasiko igba naa, awọn oyinbo amunisin lo ṣi n ṣakoso Naijiria ko to di pe Naijiria gba ominira lẹyin ọdun mejidinlogun si igba naa.
Ọmọ ọdun mẹrin ni Buhari wa nigba ti baba rẹ, to jẹ iran Fulani, jade laye, ti iya rẹ, to tọ dagba, si jẹ ẹya Kanuri. Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan lọdun 2012, Buhari sọ pe oun ni ọmọ kẹtalelogun baba oun nigba ti oun jẹ ọmọ kẹtala fun iya oun. O ni ohun iranti kan ti oun ni nipa baba oun ni igba ti wọn ti baba oun, ọmọ baba oun kan ati oun jabọ lori ẹṣin.
Ni ilu Daura ni Buhari ti lọ si ile ẹkọ alakọobẹrẹ, to si lọ sile ẹkọ girama ni igboro ilu Katsina. Lẹyin naa lo tẹsiwaju lọ si ile ẹkọ ologun Nigerian Military Training College, to si darapọ mọ ileeṣẹ ologun Naijiria lẹyin ti Naijiria gba ominira.
Buhari lọ fun idanilẹkọọ awọn ologun ni UK laaarin ọdun 1962 si 1963 to si bẹrẹ si ni goke lẹnu iṣẹ lẹyin igba naa.
Lẹyin ọpọ ọdun, Buhari sọ pe iwa ikoraẹni ni ijanu ti oun ni, to si jẹ ẹni ti ko gba gbẹrẹ, jẹ ipa gbigbe inu ọgba ile ẹkọ fun ọpọ ọdun nibi to jẹ pe awọn ijiya nla ni wọn maa n koju ti wọn ba ṣẹ, ati nidii iṣẹ ologun. O sọ pe oriire lo jẹ fun oun lati dagba ni iru awọn ayika to le bẹẹ, nitori o kọ oun bi eeyan ṣe maa n muṣẹ ni okunkundun.
Ni ọdun 1966, iditẹgbajọba waye ni Naijiria – asiko tawọn ologun n mu ayipada ba eto iṣejọba Naijiria ṣugbọn Buhari maa n sọ pe oun ko tii goke agba lẹnu iṣẹ lati kopa to ṣe koko ninu awọn iditẹgbajọba naa.
Laaarin ọdun mẹwaa si igba naa, labẹ ijọba ologun, Buhari goke agba lẹnu iṣẹ, o si di gomina ẹkun ila oorun ariwa Naijiria eyi ti ipinlẹ mẹfa wa labẹ rẹ.
Ko to o pe ọdun kan, Buhari tun ri igbega mii to si di kọmiṣanna ijọba apapọ fun epo bẹntiroolu atawọn ohun alumọni (eyi ti a le fi we minisita fun eporọbi) lọdun 1976 lasiko Olusegun Obasanjo kọkọ ṣe olori Naijiria gẹgẹ bi ologun.
Iwa palapala ati ajẹbanu
Nigba ti yoo fi di ọdun 1978, Buhari di ọgagun.
Titi di akoko yii ni awọn eeyan to n gbe ni ila oorun ariwa Naijiria, ṣi n ranti igbesẹ to gbe ati bo ṣe duro lori ipinnu rẹ lasiko ti awọn ọmọ ogun Lake Chad gba awọn erekusu kan to jẹ ti Naijiria - lẹyin to di gbogbo ọna agbegbe naa pa, to si le awọn to tasẹ agẹrẹ.
Nigba ti yoo fi di opin ọdun 1983, iditẹgbajọba mii waye tako aarẹ alagbada, Shehu Shagari, eyi to sọ Buhari to ti di ọgagun nigba naa, di aarẹ ologun orilẹede Naijiria.
Gẹgẹ bi ohun to sọ, ko si lara awọn to pete iditẹgbajọba naa, bo tilẹ jẹ pe wọn yan an sipo lati ọwọ awọn to ni agbara lọwọ amọ ti wọn kan fi oun di gẹrẹu sipo.
Amọ ṣa, awọn akọsilẹ kan sọ pe ipa to jọju ni Buhari ko ninu bi wọn ṣe yọ Ṣhagari nipo.
Ogun oṣu ni Buhari fi ṣe ijọba ologun - asiko ti ọpọ eeyan ko le gbagbe lailai paapaa igbogun ti iwa palapala ati ajẹbanu, to fi mọ titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ to kọwọrin pẹlu awọn igbesẹ rẹ.
Awọn oloṣelu to to ẹẹdẹgbẹta (500), awọn oṣiṣẹ ijọba ati awọn oniṣowo lo deero ẹwọn gẹgẹ bi ọkan lara igbesẹ rẹ tako inakuna ati iwa ibajẹ.
Awọn eeyan kan ri eyi gẹgẹ bi lilo ọwọ agbara ologun, amọ ṣa, awọn kan tun gboriyin fun igbesẹ naa, ti wọn si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ọna lati gbogun ti iwa ibajẹ to n ṣe idiwọ fun idagbasoke Naijiria.
Aṣọ ala Buhari ko ni abawọn kankan rara nipa ti jijẹ olotitọ, eyi to ṣọwọn laarin awọn oloṣelu Naijiria - ologun ati alagbada - paapaa nitori bo ṣe gbogun ti i.
Gẹgẹ bi ara igbogun ti iwa palapala, o sọ ọ di dandan fun awọn ọmọ Naijiria lati maa to si ori ila ni ibudokọ, labẹ idari awọn sọja to mu ẹgba da ni. Awọn oṣiṣẹ ijọba to ba pẹ de ibi iṣẹ ma n koju ifiniṣẹlẹya ni gbangba nipa fifo bi ọpọlọ.
Diẹ lara awọn ilana iṣejọba rẹ jẹ nnkan iyalẹnu, amọ awọn iyoku jẹ ifiyajẹni, paapaa ofin to de ominira awọn akọroyin, eyi to sọ ọpọ akọroyin di ero ẹwọn.
Ijọba Buhari tunti ogunna gbongbo akọrin, Fela Kuti mọ ẹwọn, fun bo ṣe ma n bu ẹnu atẹ lu awọn olori. Ẹsun kiko owo lọ silẹ okeere ni wọn fi kan an.
Igbiyanju Buhari lati mu apo asunwọn ilu pada sipo, nipa fifi opin si kiko ọja wọle lati ilẹ okeere, sọ ọpọ eeyan di alainiṣẹ, ti awọn okowo kan si kogba wọle.
Gẹgẹ bi ara ọna lati gbogun ti iwa ajẹbanu, o tun paṣẹ pe ki wọn o paarọ awọ owo naira - eyi to mu ki awọn eeyan o sa kijokiji lati paarọ owo atijọ si tuntun laarin asiko perete.
Owo ọja le si i, awọn eeyan ko si rowo ra wọn. Lọdun 1985, wọn yọ Buhari kuro ni ipo, o si ṣẹwọn fun ogoji oṣu. Lẹyin naa ni Ọgagun Ibrahim Babangida gba ijọba.
Aṣeyọri ninu idibo to fi itan balẹ
Lẹyin itusilẹ rẹ, o ni lẹyin ti oun fi oju ri atunbọtan ipinya Soviet Union, Buhari pinnu lati darapọ mọ oṣelu.
Lasiko yii, o ti mọ iyi iṣejọba awaarawa to ni akojọpọ ọpọlọpọ ẹgbẹ oṣelu ati eto idibo to lọ lai si ija.
Pẹlu eyii, Buhari ni oun ko jẹbi pẹlu iditẹgbajọba ọdun 1983. O sọ lọdun 2005 pe "Ijọba ologun gba ijọba lasiko to ṣe koko, nitori awọn eeyan ti a dibo yan ti ja ilu kulẹ."
Bakan naa lo tako ẹsun ti wọn fi kan an pe, iha to kọ si awọn akọroyin ati awọn mii ti lagbara ju - o tẹnumọ pe nnkan ti oun ṣe koju pe oun fẹ ki wọn tẹle ofin ti awọn kan ko kọ ibi ara si.
O wọle ibo aarẹ ni ọdun 2015, to si di ẹni akọkọ lati ẹgbẹ oṣelu alatako ti yoo fi idi ẹni to wa nipo aarẹ janlẹ lati ibẹrẹ ijọba awaarawa ni ọdun 1999.
Gẹgẹ bii aarẹ, Buhari jẹ olori to tako iwa jẹgudujẹra, to si jẹ ko di mimọ pe ọpọ nnkan ni oun kọyin si lati sọ ara oun di olowo.
Bo ti lẹ jẹ pe ọpọ eeyan ni ko gbagbọ pe o n gbe ogun ti iwa ibajẹ, ti ibeere si bẹrẹ si ni jẹyọ pe boy ani eyi wa si imusẹ.
'Apo Irẹsi'
Ni ọjọ ti Buhari kuro ni ipo ààrẹ, wọn bí àwọn ọmọ Naijiria kan ni ìbéèrè pé kí ni wọn kò le gbagbe laelae nípa sáà isejọba ààrẹ Buhari ?
Fidio naa si ni o gbalẹ kan lori ayelujara.
Idahun gbogbo awọn eeyan ti wọn bi ni ibeere naa ko si yàtọ̀ sira wọn: 'Apo Ìrẹsì'.
Idi ti wọn fi dahun bakan naa ko si soro lati mọ rara - ìrẹsì jẹ oúnjẹ to wọ́pọ̀ ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Apo ìrẹsì to jẹ aadọta kilogiramu (110lb), èyí to le bọ idile ẹlẹni mẹ́jọ si mẹ́wàá fun oṣu kan, ní wọn n ta ni Ẹgbẹrun meje aabọ ($5; £3) ni akoko isejọba ààrẹ Goodluck Jonathan, ẹni tí Buhari fi ẹyin rẹ janlẹ lọdun 2015, amọ apo ìrẹsì naa lo fo fẹrẹ di ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta Naira lẹ́yìn ọdún diẹ.
Eyi si mu kí ebi gbode ni ọpọlọpọ agbegbe nílẹ̀ Naijiria.
Owo nla to gun owo apo ìrẹsì naahuge nitori pe lasiko ti Buhari ṣe akoso ilẹ̀ Nàìjíríà lásìkò isejọba ológun, Buhari fi ofin de ìgbésẹ̀ kiko ìrẹsì wọle si Naijiria lọ́nà àti ṣe koriya fún àwọn àgbẹ̀ labẹle lati ṣe ọgbin ìrẹsì.
Àmọ́, àwọn ọlọgbin ìrẹsì ni abẹle ko le pese àdúrú apo ìrẹsì tawọn aráàlú n beere fún, eyi to mu kí àwọn alatilẹyin rẹ sọ igbẹkẹle wọn nínú isejọba rẹ nu.
Ismail Danyaro, olugbe ilu Kano, to wa ni apa Ariwa Naijiria, ni lati ọdún 2003 ni òun ti n ṣe àtìlẹyìn fún Buhari, èyí tíì ṣe igba àkọ́kọ́ to kọ́kọ́ díje fun ipo ààrẹ Nàíjíríà.
"Mo maa n ra àpò ìrẹsì to jẹ aadọta kilogiramu sínú ile lasiko isejọba ààrẹ Goodluck Jonathan ṣùgbọ́n nígbà tí Buhari gba akoso ìjọba, ó nira fun mi láti ra ìdajì àpò ìrẹsì to jẹ kilo mẹẹdọgbọn nitori o ti gbe owo lori pupọ ju," o sọ fún BBC.
O to asiko kan, iyawo Buhari gan dunkooko pe oun ko ni ṣe àtìlẹyìn fun iyansipo rẹ fun saa kejì.
'Baba go slow'
Awọn ọmọ Naijiria fẹran orukọ inagijẹ pupọ - orukọ ti wọn fun awọn adari kan to ti lọ ko si parẹ titi di oni yii.
Fun apẹrẹ, Aarẹ ologun tẹlẹ, Ibrahim Badamasi Babangida jẹ ẹnikan ti wọn ko yi orukọ apele rẹ "Maradona" pada. Orukọ ọhun ni wọn fun nitori bo ṣe maa n ṣe nnkan tirẹ.
Ni ti Buhari, wọn bẹrẹ si n pe ni "Baba go slow" lẹyin ti ko kede minisita rẹ akọkọ titi di oṣu kẹfa rẹ lori alefa.
Nigba to n sọrọ lori orukọ naa lẹyin ọdun diẹ si asiko ọhun, o ni kii ṣe ẹbi oun pe o gba oun lakoko diẹ ki oun to kede awọn alabaṣiṣẹ oun.
O sọ lọdun 2018 pe "Lootọ ni a ko ja fafa nitori iṣẹjọba ko ja fafa. Kii ṣe Baba ni ko ja fafa bikoṣe bi ijọba ṣe ri, mo si lero pe a ma a ṣe aṣeyọri."
Eto oṣelu Naijiria laarin ọdun 2022 si 2023 jẹ asiko to ṣe koko julọ ninu itan oṣelu Naijiria.
O jẹ igba akọkọ ti Aarẹ to wa lori oye ko bikita nipa ẹni ti yoo joko sori itẹ aarẹ lẹyin rẹ.
Buhari sọ ni gbangba pe oun yoo ṣatilẹyin fun ẹnikẹni to ba bori ibo abẹle ẹgbẹ APC.
Gbogbo awọn maraarun to n du ipo naa lo sọ pe o ṣatilẹyin fun awọn.
Lakoko igba kan, o fẹ jọ bii pe Buhari ko faramọ Bola Tinubu to pada bori ibo Aarẹ ọdun naa lọhun.
Asiko ọhun ni wọn bẹrẹ eto atuṣe owo naira, eyi ti Buhari ti sọ pe oun yoo ri daju pe ko si owo to pọ lawujọ lasiko ibo aarẹ naa.
Ọpọ araalu lo gbagbọ pe ijọba gbe igbesẹ naa lati ṣe idiwọ fun Tinubu ninu akitiyan rẹ lati di aarẹ.
Lara ohun ti wọn ṣe nigba naa ni bi wọn ṣe ko owo naira atijọ wọle ti wọn si tẹ owo tuntun.
Amọ owo naira tuntun naa ko kari gbogbo ilu, eyi to yọri si iya fun ọpọ ọmọ Naijiria.
Amọ ile ẹjọ to ga julọ kan pasẹ tako igbesẹ naa laarin ọjọ diẹ si ọjọ idibo.
Lẹyinorẹyin, Tinubu bori ibo naa pẹlu ida 37% gbogbo awọn to dibo lẹyin ti ohun awọn ẹgbẹ alatako ko ṣe ọkan.
Lasiko ijọba Buhari, o ṣaisan to bẹẹ to fi maa n lọ soke okun fun itọju, paapaa ni saa rẹ akọkọ.
Bo tilẹ jẹ pe Buhari maa n juwe ara rẹ gẹgẹ bii ẹni ti kii fi ara rẹ pamọ, ko ṣe ootọ pẹlu awọn ọmọ Naijiria nipa eto ilera rẹ.
Igba meji ọtọọtọ ni Muhammadu Buhari ṣe igbeyawo, akọkọ ni igba to fẹ Safinatu Yusuf laarin ọdun 1971 si 1988, lẹyin naa lo tun fẹ Aisha Halilu lọdun 1989. Ọmọ mẹwaa ni Buhari bi ki ọlọjọ to de.