Nàìjíríà ṣòro púpọ́ láti darí, ṣùgbọ́n mo sa ipá mi - Buhari

Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ, Muhammadu Buhari, ti ṣalaye pe ki i ṣe ohun to dẹrun lati tukọ Naijiria, ṣugbọn oun gbiyanju, oun si sa ipa oun lasiko iṣejọba ọdun mẹjọ naa.

Buhari sọ pe kekere kọ lohun toju oun ri lasiko toun n dari Naijiria, o ni inu oun dun lati fipo aarẹ silẹ, nitori boun ṣe kuro lori aleefa ti foun lanfaani lati mojuto iṣẹ oko oun.

Nibi ifọrọwerọ ti aarẹ tẹlẹ naa ṣe pẹlu ileeṣẹ tẹliṣan NTA lo ti ṣalaye pe àárò ipo toun fi silẹ yii ko sọ oun rara, kaka bẹẹ, Buhari sọ pe oun ṣọpẹ f’Oluwa fun anfaani lati dari Naijiria ni.

‘’Emi gan-an ti n foju sọna lati kuro nipo aarẹ, inu mi si dun bo ṣe pari. Mo n lọ soko mi mo si n ṣere idaraya, mo n ri awọn nnkan ọsin mi. Igba to wu mi ni mo n ji, igba to ba si wu mi ni mo n jade’’

"Mi o kọle kankan, mi o fowo ra ileeṣẹ, mi o si ba Naijiria du nnkan kan, ohun to jẹ ki n maa gbe lalaafia niyẹn"

Nipa boya iṣakoso rẹ rọ araalu lọrun, Buhari loun ṣewọn toun le ṣe, iyooku ku sọwọ awọn ọmọ Naijiria.

‘Mi o foju tẹmbẹlu Naijiria’

Aarẹ tẹlẹ naa ṣalaye, pe oun ko fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ Naijiria nigba toun wa nipo, eyi ko si jẹ koun le kọju mọ awọm iṣoro mi-in to ti ilẹ okeere wa.

O fi kun un pe ko sẹni to le dari Naijiria ti ko ni i rẹjọ ro, o ni o ṣoro pupọ lati dari orilẹ-ede yii nitori awọn eeyan ibẹ gbọn pupọ, wọn si mọ ẹtọ wọn.

“ Awọn iṣoro Naijiria gan-an ti gba gbogbo akoko mi tan, mi o ki n le ronu nipa awọn iṣoro to n ti ibo mi-in wa, afi ti ẹnuubode (border) ti wọn tipa to si ṣe pataki lati mojuto.

“ Mi o kọle kankan, mi o fowo ra ileeṣẹ, mi o si ba Naijiria du nnkan kan, ohun to jẹ ki n maa gbe lalaafia niyẹn lati oṣu mẹfa ti mo ti fipo aarẹ silẹ.

Awọn ọmọ Naijiria mọna ti wọn le gba mọ ẹni to ba yan wọn jẹ, ti wọn yoo si fọwọ ofin mu un.

‘’Wọn gbọn, wọn maa gba ẹ niyanju titi to o maa fi ṣe aṣisẹ kan, to maa waa di pe keeyan wa ṣalaye bo ṣe kowo si Saudi abi ibomi-in, tori ẹ ni mo ṣe ṣọra mi. “

"Tawọn eeyan ba sọ pe awọn onijẹkujẹ lo yi mi ka, wahala ti wọn niyẹn"

Nigba to n sọrọ nipa bo ṣe dupo aarẹ titi ti ko tete bọ soju ẹ, Buhari sọ pe ọpọ eeyan lo n foun ṣe yẹyẹ nigba naa, ti wọn ko kaanu oun rara.

O ni ṣugbọn pẹlu iranlọwọ imọ ẹrọ ati lilo kaadi idibo (PVC), oun pada wọle sipo aarẹ.

Ọwọngogo naira to ṣẹlẹ to si ko idaamu ba ọrọ-aje, Buhari sọ pe nitori ipele idagbasoke to n lọ lọwọ ti Naijiria wa ni.

O pari ifọrọwerọ naa pẹlu bawọn eeyan ṣe gbagbọ pe awọn aworoṣaṣa kan (cabal), yi ijọba rẹ ka, awọn alajẹbanu si ni wọn, awọn ni wọn si n dari Naijiria nigba naa.

Buhari ṣalaye pe ko sẹni to gba iṣakoso mọ oun lọwọ, nitori oun ko gba ki wọn fọwọ kan owo ilu fun lilo ara wọn.

“ Tawọn eeyan ba sọ pe awọn onijẹkujẹ lo yi mi ka, wahala tiwọn niyẹn.

Ko sẹni to kọja ofin, emi o si ni ẹnikẹni to kowo ilu yii jẹ to si lọ bẹẹ ninu ijọba mi.

Mi o ki n gba ki wọn fowo ilu ṣara rindin’’

Bẹẹ ni Muhammadu Buhari wi.