You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ààrẹ Naijiria tẹ́lẹ̀, Muhammadu Buhari ti jáde l'áyé
Aarẹ Naijiria nigba kan, Muhammadu Buhari ti jade laye lẹni ọdun mejilelọgọrin.
Ọsan ọjọ Aiku, ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2025 ni oluranlọwọ pataki fun , Garba Shehu, fi ikede iku rẹ sita fun awọn akọroyin.
Shehu sọ pe ileewosan kan niluu London ni Buhari ku si.
Oṣu Kẹrin ni iroyin sọ pe aarẹ tẹlẹ ọhun ti lọ si United Kingdom, nibi to ti lọ fun ayẹwo ilera, ko to o di pe o dubulẹ aisan.
Ibẹẹrẹ aye Buhari
Muhammadu Buhari ni wọn bi ni ọdun 1942 si idile Musulumi nipinlẹ Katsina, to si lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni ọdun 1948 si 1952, ati ile ẹkọ aarin ni ọdun 1953.
Lẹyin ọdun mẹta, Buhari lọ si ilẹ ẹkọ girama Katsina Provincial Secondary School (ti wọn n pe ni Government College, Katsina bayii) to si kẹkọ lati ọdun 1956–1961, to si gba iwe ẹri WAEC.
O darapọ mọ ileeṣẹ ologun ni ọdun 1961, to si de ipo giga. Ajagun fẹyinti naa kopa ninu iditẹgbajọba ni ọdun 1983, to si ṣe ijọba ologun lẹyin naa fun ogun oṣu ko to di pe wọn gba ijọba lọwọ rẹ. O jẹ eeyan kan ti ko gba gbẹrẹ, to si jẹ akinkanju olori
Ijọba ologun rẹ lo ṣe agbekalẹ ohun ti a n pe ni War Against Indiscipline ni ọdun 1984 lati fọ ilẹ Afrika mọ. Awọn ologun n fi tipatipa mu awọn eeyan to ati titẹle ofin oju opopna. Awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn ba pẹ de ibi iṣẹ ni wọn koju ifiyajẹni.
Eyi ṣe akoba nla fun irinajo rẹ sinu oṣelu fun ọpọ ọdun. Ọdun 2015 lo to o bori ibo lẹyin ọpọ igbinyanju. Igba mẹta ọtọọtọ lo padanu eto idibo aarẹ lorilẹede Naijiria.