You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Ọmọ tálákà ni mí, mi ò mọ olóṣèlú kankan kí n tó di ayàwòrán Ààrẹ Buhari'
Yoruba ni, ori ti yoo ba sọre, ko si ohunkohun to le di i lọwọ.
Bẹẹ gan-an lo ri fun Ọgbẹni Bayo Omoboriowo, to jẹ ayaworan fun Aarẹ orilẹ-ede Naijiria nigba kan, Muhammadu Buhari.
Ọdun mẹjọ ni Ọgbẹni Omoboriowo fi ya aworan fun Aarẹ Buhari, ni Naijiria, ati ni gbogbo ibi to ba lọ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC Yoruba, o sọ pe oun ko mọ oloṣelu kankan tabi wa lati idile olowo, ki oun to o di ayaworan fun aarẹ.
Koda, Omoboriowo sọ pe kii ṣe ala ti oun la.
“Kii ṣe ala to ṣe e la ni pe ma a ba aarẹ joko, tabi rin awọn irinajo ti a rin.”
O ni mọ atẹrf dide ni oun, ti igbeaye si nira pupọ nigba ti oun wa ni kekere.
Onmoboriowo to jẹ akẹkọọ nipa imọ Kẹmisiri ni Fasiti Unilag, sọ pe ifẹ ti oun ni si aworan yiya lo gbe oun de ipo nla naa.
“Lati ile ẹkọ ni mo ti ma n ya aworan fun awọn eniyan, botilẹ jẹ pe mo ma n ya ẹrọ ayaworan lọpọ igba.”
O ni akiyesi ti oun ni, nipa bi awọn ayaworan kii ṣe e ya awpran awọn oloṣe;u tabi awọn to wa ni ijọba daadaa, paapaa bi oun ṣe n ri ni oju iwe iroyin.
Ọgbẹni Bayo Omoboriowo ṣalaye pe lasiko ipolongo ibo ṣaaju idibo ọdun 2015, ni oun deedee pinnu lati lọ si gbagede TBS, to wa niluu Eko.
Erongba to ni lọkan ni lati ya awọn aworan awọn oloṣelu nibi ipagọ naa, pẹlu ireti pe ẹnikan yoo ṣaanu rẹ lati ko awọn aworan naa fun awọn to wa ninu rẹ.
Ibi to ti n ya awọn aworan naa ni wọn ti ji foonu mọ ọ lara.
Ibanujẹ dori agba kodo wayii.
Omoboriowo sọ pe ibanujẹ ọkan oun lọjọ naa ni oun fi gbadura si Ọlọrun, lati ma jẹ ki iya naa jẹ oun gbe.
Bakan naa lo sọ pe ṣaaju asiko naa ni oun ti ma n fi awọn aworan ti oun ba ya, si ori ayelujara fun araye lati ri.
“Mo kan gba ipe lọjọ kan, pe wọn n wa ẹni ti yoo ma a ya aworan nibi ipolongo ibo fun Ọgagun Muhammadu Buhari.
“Owo ti wọn fẹ ẹ fun mi kere, mo si sọ fun wọn pe mi o le ṣe e.”
O ni o ku jọ kan ti ipolongo ibo aarẹ yoo bẹrẹ niluu Port Harcourt, ni ẹmi kan sọ si oun lọkan pe, ṣebi kii ṣe ifẹ owo ni oun fi bẹrẹ isẹ ayaworan.
Eero naa lo mu ko pinnu lati ṣe iṣẹ ọhun, botilẹ jẹ pe ko si owo to nitumọ ni bẹẹ.
“Ọpọ igba ni kii ṣi aaye fun mi lati joko ninu baalu. Inu ile igbọnsẹ ninu baalu ni mo ma n jokoo si nigba miran.
“Awọn ọjọ kan ti ẹ wa ti wọn ma n ja mi ju silẹ ni papakọ ọkọ ofurufu, ṣugbọn mi o ni pada sile.
“Niṣe ni ma a ṣa duro pa sibẹ, debi i pe wọn a tun ba mi ti wọn ba de pada.”
A ṣe lootọ ni pe ko si aṣepamọ. Gbogbo igbiyanju Bayo, ati iru awọn aworan to n ya ni Buhari n ri.
Bayo Omoboriowo sọ pe ni kete ti aarẹ wọle ninu ibo, lo deedee bere oun pe ki wọn o wa oun kan lati ṣiṣẹ fun oun gẹgẹ bi ayaworan.
Ọgbẹni Omoboriowo sọ pe o le ni ọgọrin orilẹ-ede ti oun ba Aarẹ rinrinajo de laarin ọdun mẹjọ.