Ètò ààbò àti ọrọ̀ ajé ṣe dáadáa púpọ̀ lásìkò ìjọba mi - Buhari

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Muhammadu Buhari, ti ṣalaye pe eto aabo ati ọrọ aje ṣe daadaa, bẹẹ lo gbeeru si i lasiko ijọba ọdun mẹjọ ti oun ṣe lorilẹede yii.

Buhari sọrọ naa lasiko to n gbalejo awọn akọroyin ileeṣẹ iroyin labẹ ẹgbẹ awọn akọroyin ẹka ti ipinlẹ Katsina ti wọn wa bẹẹ wo ni ile rẹ ni ilu Daura.

Nibi ipade naa ni Buhari ti sọ pe oun ranti pe aabo ati ọrọ aje ti foriṣanpọn lorilẹede yii ki oun to de.

O ni nigba ti oun di aarẹ ni ijọba oun koju awọn iṣoro naa.

Aarẹ Buhari sọ pe, awọn to wa ni iṣakoso ijọba lorilẹede Naijiria lo le mọ iṣoro to wa ninu ṣiṣakoso orilẹede Naijiria. o fi kun un pe oniruuru iṣoro ati idiwọ lawọn adari maa n dojukoso ninu iṣakoso ijọba lorilẹede Naijiria.

" Eto aabo ati ọrọ aje gbeeru daadaa labẹ iṣakoso mi ni Naijiria, ti a ba fi we ohun ti mo ba nigba ti mo gbajọba ni 2015.

Aarẹ tẹlẹ naa tun ṣalaye pe o da oun loju pe nnkan yoo maa daa si i ni Naijiria ni.

O ni ọgbọn aabo ati ọrọ aje toun lo, yanju iṣọro ju ti tawọn toun gbajọba lọwọ wọn lọ.

Buhari sọ pe awọn to wa nipo agbara nikan ni wọn le mọ ipenija to n koju Naijiria.

O ni kekere kọ loju awọn olori n ri ki wọn too ṣẹgun iṣoro orilẹede wọn .