Afurasí agbésùnmọ̀mí Lakurawa ṣekúpa ọlọ́pàá mẹ́ta ní Kebbi, agbébọn 400 kojú ọmọ ogun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi Lakurawa ti ṣekupa ọlọpaa mẹta, ti awọn araalu eji mii si farapa ninu ikọlu kan to waye nipinlẹ Kebbi.

Oju ọna Tiili, to wa ni ijọba ibilẹ Bunza ni iṣẹlẹ ọhun ti waye lasiko ti wọn n gbiyanju lati ji awọn arinrinajo kan gbe nibẹ.

Iroyin ni kete ti awọn ọlọpaa agbegbe Zogirma gbọ nipa ijinigbe naa ni wọn kesi awọn ọlọpaa 36 Police Mobile Force Squadron ni Birnin Kebbi ti wọn si tẹkọ leti lọ sagbegbe naa.

Awọn ọlọpaa naa atawọn ajinigbe ọhun koju ija si ara wọn ti iro ibọn si n dun lakọlakọ, nibi ti ọlọpaa mẹta ti padanu ẹmi wọn.

Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kebbi, Nafiu Abubakar lo fi alaye naa lede ninu atẹjade kan.

Atẹjade naa fi kun pe pupọ ninu awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi naa lo padanu ẹmi wọn niui ija ọhun.

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa, Bello Sani, ti kan saara si awọn ọlọpaa to kọju si ija awọn ajinigbe naa fun akinkanju wọn.

Nigba to n sọrọ, gomina ipinlẹ ọhun, Nasir Idris sọ pe lootọ ni awọn ọlọpaa jade laye lasiko ti wọn n koju awọn agbesunmọmi naa, lẹyin naa lo sun ipade awọn ọmọ ẹgbẹ APC kan to yẹ waye ni Birnin Kebbi siwaju.

Agbesunmi bii 400 kọlu ilu mii, ologun da wọn duro

Ẹwẹ, awọn ọmọmogun 223 Light Battalion, ni Zuru ti bori awọn agbesunmọmi to kọlu ilu Ribah, ni ijọba ibilẹ Danko Wasagu, ni ipinlẹ Kebbi.

Iroyin ni awọn agbebọn bii irinwo lo kọlu ilu naa ki awọn ọmọ ogun 223 Light Battalion to kọju ija siwọn, ti wọn si le awọn agbebọn naa jina rere.

A gbọ pe niṣe ni iro ibọn n dun lakọlakọ lasiko ija naa amọ awọn ọmọ ogun bori ti pupọ ninu awọn agbesunmọmi ohun si gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko diẹ lara oku awọn akẹgbẹ wọn lọ, pupọ ninu wọn ni oku wọn wa loju titi, pẹlu ọpọ ohun ija oloro ti wọn ko sọdi.

Adari eto lagbegbe ọhun, AbdulRahman Zagga sọ pe lootọ ni ija naa waye, o si gboriyin fun awọn ọmọ ogun fun iṣẹ takuntakun ti wọn.

O ni ṣe lawọn agbesunmọmi ọhun maa n dunkọkọ mọ awọn ni gbogbo igba ti ọkan wọn ko si balẹ amọ inu awọn dun pe awọn ologun ti fi imu awọn agbesunmọmi naa danrin.