You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Àwọn òbí mi rò pé mo ti jóná mọ́lé, láì mọ̀ pé ìbátan bàbá mi ló jí mi gbé fi ṣọmọ'
- Author, BBC News Mundo and BBC Global Journalism
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Iya kan gbọ ariwo nla kan. O si goke ninu ile rẹ lati ṣawari pe ina ti sọ ninu yara ti ọmọ rẹ kekere jojolo wa.
O wo ibi to gbe ọmọ naa si amọ ko ri ọmọ ọhun nibẹ.
Oru ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 1997 ni iṣẹlẹ naa waye nile tọkọtaya kan, Luz Cuevas ati Pedro Vera ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Pueto Rico ṣugbọn ti wọn n gbe nilẹ Amẹrika.
Ọlọpaa ni awọn waya ina kan to kanra wọn lo ṣokunfa ina ọhun. Amọ lẹyin ọpọ iwadii, wọn ko mọ ibi ti ọmọ wọn, Delimar wọ ilẹ si, wọn si gbagbọ pe o ti ku sinu ina ọhun to ṣẹyọ nile wọn.
Iṣẹlẹ naa ba tọkọtaya naa lọkan jẹ amọ wọn ko mọ pe ibẹrẹ ibanujẹ wọn niyẹn.
Ṣaaju ki ina ọhun to ṣẹyọ, ẹnikan kan ilẹkun ile wọn, Luz ṣilẹkun naa, o si pade Carolyn, to jẹ ibatan Pedro ọkọ rẹ, lẹnu ọna.
Carolyn sọ fun Luz pe oun fẹ ba Pedro sọrọ nitori oun ni iṣẹ kan fun un.
Awọn mejeji si jọ jade lọ lati sọrọ nipa iṣẹ naa, amọ ko pẹ lẹyin naa ti Carolyn pada sile wọn pe oun gbagbe apo apamọwọ oun, ati pe oun fẹ lọ ṣẹyọ ni iyara to wa loke ile wọn.
Lẹyin akoko diẹ ni Luz gun yara oke naa lati wo ọmọ ọjọ mẹwaa pere to tẹ si ori ibusun, o si ri pe ọmọ naa ko si nibi ti oun gbe si mọ lẹba ferese.
Nigba ti Carolyn jade ninu ile iyagbẹ ti Luz si bere lọwọ rẹ eredi to fi gbe ọmọ naa kuro nibi to wa ṣaaju, o ni oun ṣe bẹẹ ko ma ba a ṣeṣe ni.
Lẹyinorẹyin, Carolyn jade lọ. Amọ ko pẹ lẹyin ti alejo wọn naa lọ tan ti Luz gbọ ariwo kan ninu yara to wa loke naa, nigba ti yoo fi gun oke lọ, o ri pe ina ti sọ nibẹ.
O wa ọmọ rẹ, Delimar to tẹ sori ibusun rẹ ninu ina ati eefin amọ ko ri ọmọ tuntun ọhun.
Laarin iṣẹju diẹ, awọn oṣiṣẹ panapana de, wọn si pa ina ọhun.
Awọn panapana gbe ibusun ọmọ naa ti ina jo ku, wọn fun awọn obi rẹ, wọn si sọ fun wọn pe oku ọmọ wọn ti ina jo ku niyẹn.
Ayẹyẹ ọjọ ibi ti akara ti tu sepo
Akoko ti iṣelẹ yii waye ni Carolyn funra rẹ ti loyun to si sọ pe oun n reti lati bi ọmọ oun ikẹrin.
Lọjọ ikunlẹ ti yoo bimọ, obinrin lo bi, o ni ile oun to wa ni ogun kilomita sile tọkọtaya ti ina ti ṣẹyo loun bimọ si dipo ile iwosan.
Nigba ti yoo di ọdun 2004, wọn ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi kan nile ibatan Pedro.
Ni kete ti Luz de ile ti ayẹyẹ ọjọ ibi naa ti n waye, o ri ti Carolyn gbe ọmọdebinrin kan lọwọ, o si ṣakiyesi pe tọọrọ ẹrẹkẹ ọmọ naa jọ eyii to ti ri nibikan ri.
Ni kete to ri ọmọ naa lo ke gbajare pe ọmọ oun Delimar ni.
Nigba ti ọmọ kekere naa lọ ba awọn akẹgbẹ rẹ ṣere, Luz sọ fun pe "jẹ ki n ba ẹ yọ nnkan to wa ni irun rẹ."
Asiko naa lo fi ọgbọn agba ge lara irun ọmọ naa.
Nigba ti Carolyn ṣakiyesi ohun to n ṣẹlẹ, o sọ fun tọkọtaya naa pe asiko ti to ki wọn maa lọ sile wọn.
Ayẹwo nile iwosan
Lẹyin ọsẹ diẹ, Carolyn gbe ọmọ naa, Aaliyah ati ọmọ rẹ obinrin mii lọ ri dokita.
Ibi ti wọn ti n duro de asiko wọn lati ri dokita ni dokita naa ti fi ọgbọn mọ mu Aaliyah wọ inu iyara kan.
Inu yara naa lo ti bu nnkan bii omi si lẹnu, to si fi ohun elo mii fa ahọn rẹ.
Lai mọ ohun to n ṣẹlẹ, ayẹwo DNA ni dọkita naa n ṣe.
Latari pe o ti ni irun lọwọ tẹlẹ, Luz kan si awọn ọlọpaa lati ṣayẹwo DNA tiwọn pẹlu.
O tun kan si aṣofin kan ati agbẹjọro lati gbe ọrọ naa yẹwo.
Ninu oṣu keji ọdun 2004 ni iwadii fi han pe Aaliyah, to ti pe ọmọ ọdun mẹfa ni Delimar ọmọ Luz ti wọn ro pe o ti ku ninu ina to ṣẹyọ nile wọn.
Niṣe ni Carolyn parọ pe oun loyun to si ji ọmọ kekere naa gbe.
Lẹyin ọpọ ẹjọ, Carolyn jẹwọ pe lootọ loun ji ọmọ naa gbe, wọn fẹsun ijingbe kan an, o si dero ẹwọn.
Ọmọ kan, iya meji
Iroyin naa ba inu Delimar jẹ gidi.
Nigba to n sọrọ, o ni ibeere to wa lọkan oun lasiko naa ni "kilode ti ẹ fẹ gbe mi kuro lọdọ iya mi?"
O tun sọ pe oun ko kọkọ fẹran orukọ oun Delimar nigba to bẹrẹ si gbe n lọdọ iya atawọn aburo rẹ ti wọn jẹ ajeji si i.
Lẹyinorẹyin, Delimar gba f'Ọlọhun, o si bẹrẹ igbeaye tuntun lọdọ awọn obi rẹ tootọ.
Amọ iṣẹlẹ naa bi ninu pupọ to si maa n ṣabẹwo si iya rẹ atijọ ninu ọgba ẹwọn lati bu ẹnu atẹ lu u.