Wo Awùjalẹ̀ 56 tó jẹ́ ṣaájú Ọba Sikiru Kayode Adetona tó wàjà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awujalẹ ni orukọ oye fun ọba alade nilẹ Ijẹbu. Gẹgẹ bi ojuṣe rẹ, Awujalẹ lo jẹ olori fun gbogbo awọn ọba yooku kaakiri ilẹ Ijẹbu.

Ilẹ Ijẹbu jẹ ọkan gboogi lara awọn ilu to kọkọ tẹdo nilẹ Yoruba, lati igba atijọ si ni wọn ti n ni adari.

Awujalẹ to ṣẹṣẹ waja, Ọba Kayode Adetona Ogbagba II, ti jẹ lati ọdun 1960 titi di ọjọ kẹtala oṣu Keje, ọdun 2025.

Idile Anikilaya si lo ti wa.

Gẹgẹ bi abala ofin kẹrin ti ọdun 1957 fun Western Region, idile mẹrin lo le jẹ Awujalẹ ilẹ Ijẹbu. Awọn idile naa ni:

Idile Gbelegbuwa

Idile Anikinaiya

Idile Fusengbuwa

Idile Fidipote

Ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹjọ, ọdun 1959, ni wọn ṣe agbekalẹ naa, ti ijọba si buwọlu u lọjọ kini oṣu Kẹsan an, ọdun 1959 bakan naa.

Awọn Awujalẹ mẹrindinlọgọta to jẹ ṣaaju Sikiru Kayode Adetona

Ṣaaju ki Awujalẹ Adetona to o jẹ, Awujalẹ mẹrindinlọgọta lo ti jẹ, gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe sọ.

Akojọpọ wọn re e:

Oba Olu-Iwa (Oun ni itan sọ pe o tẹ ilẹ Ijẹbu do)

Oba Oshin

Obanta – 1430

Oba Guru – 1445

Oba Munigbuwa – 1455

Obanta II – 1460

Oba Loja – 1470

Oba Lofin – 1482

Oba Apasa – 1496

Oba Ganju – 1508

Oba Tewogboye – 1516

Oba Ruwamuda – 1520

Oba Ofinran – 1532

Oba Lapengbua – 1537

Oba Otutubiosun – 1537

Oba Moko Idowa Ajuwakale – 1540

Oba Adisa – 1552

Oba Abimbola - 1555

Oba Jewo – 1561

Oba Elewu Ileke – 1576

Oba Olumisodan Elewu Ileke – 1590

Oba Mase – 1620

Oba Olotuseso – 1625

Oba Mola – 1635

Oba Ajana – 1642

Oba Ore tabi Gadegun – 1644 (Oun ni Awujalẹ akọkọ to jẹ obinrin)

Oba Gunwaja – 1655

Oba Jadiara Or Olowojoyemeji – 1660

Oba Sapokun – 1675

Oba Falokun – 1687

Oba Mekun – 1692

Oba Gbodogi – 1702

Oba Ojigi Amoyegeso – 1710

Oba Liyewe Arojofaye – 1730

Oba Moyege Olope – 1730

Oba Ojora – 1735

Oba Fesojoye – 1745

Oba Ore Jeje – 1749 (Female)

Oba Sapennuwa Ruba Koye – 1750 (Obinrin keji to jẹ Awujalẹ)

Oba Orodudu Joye – 1755

Oba Tewogbuwa I – 1758

Oba Gbelegbuwa I – 1760

Oba Fusengbuwa – 1790

Oba Setejoye – 1820

Oba Anikilaya Figbajoye Agboogunsa – 1821

Oba Afidipotemole Ademuyewo – 1850

Oba Atunwase Adesinbo – 1886

Oba Ogbagba Agbotewole I – 1895

Oba Fusigboye Adeona – 1906

Oba Fesogbade Ademolu – 1916 (Wọn rọ ọ loye, amọ o tun pada sori itẹ lọdun 1917)

Oba Adekoya Eleruja – 1916

Oba Ademolu Fesogbade – 1917 (O pada sori itẹ)

Oba Adenuga Afolagbade – 1925

Oba Ogunnaike Fibiwoga – 1929–1933

Oba Daniel Adesanya Gbelegbuwa II – 1933–1959

Oba Dr. Sikiru Oluwakayode Adetona, Ogbagba Agbotewole II– 1960–2025