Tinubu, Atiku, Makinde, Ooni àti àwọn èèkàn ìlú n ṣe ìdárò Buhari

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ eekan lorilẹede Naijiria lo ti bẹrẹ si ni ma ba idile aarẹ tẹlẹ, Muhammadu Buhari kẹdun lẹyin to jade laye lọjọ kẹtala oṣu Keje, ọdun 2025.

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Bayo Onanuga fi sita ṣalaye pe, Tinubu ti kan si iyawo oloogbe, Aisha Buhari lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ, to si kẹdun pẹlu idile naa.

Aarẹ Tinubu ni pẹlu ibanujẹ ọkan ni oun fi gba iroyin iku aarẹ ana, Ọgagun fẹyinti Muhammadu Buhari, GCFR, ẹni to gba ijọba lọwọ rẹ lọdun 2023.

Tinubu ṣapejuwe Buhari gẹgẹ bii olori ati ologun to nifẹ araalu, to si fi ọkan sin orilẹede Naijiria titi to fi jade laye.

Bakan naa, Aarẹ Tinubu tun paṣẹ fun igbakeji rẹ, Kashim Shettima ati akọwe agba fun ijọba, Femi Gbajabiamila pe ki wọn lọ si orilẹede United Kingdom nibi ti Buhari ku si, lati tẹle oku oloogbe pada si Naijiria.

Yatọ si eyi, o tun paṣẹ pe ki asia orilẹede Naijria sọkalẹ si agbedemeji ọna kaakiri orilẹede Naijiria.

Atiku, Ooni, Makinde, Obi, Ngozi Okonjo-Iweala sọrọ lori iku Buhari

Oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo to kọja, Atiku Abubakar ti ṣapejuwe oloogbe Buhari gẹgẹ bii olori to ni ifẹ ilu ju ara rẹ lọ

Atiku ni Buhari ki n ṣe olori ilu, ṣugbọn awọkọse nla fun orilẹede Naijiria lati ma jawọ ninu igbiyanju lati di ibi ogo.

O ṣapejuwe ipadanu yii gẹgẹ bii eyi ti ki ṣe ti idile rẹ ati awọn eeyan Daura nikan ṣugbọn ti gbogbo Naijiria.

"Naijiria padanu olori to fi ọkan siṣẹ fun ilu, ti orukọ rẹ ko si le parẹ laye."

Gbogbo nnkan ti Buhari ṣe lasiko to wa ni ipo aarẹ lo jẹ manigbagbe - Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde naa ti pẹlu awọn eeyan to kẹdun pẹlu idile Aarẹ ana, Muhammadu Buhari ati Aarẹ Bola Tinubu lori iku aarẹ ana naa.

Ninu atẹjade ti ọfisi gomina fi sita, Makinde gba ladura pe ki Ọlọrun duro ti iyawo oloogbe ati gbogbo idile Buhari

Gomina ṣapejuwe iku oloogbe gẹgẹ bii eyi ti ọpọ ko ro lọkan pe o ya bayii ṣugbọn o jẹ ko di mimọ pe gbogbo nnkan ti Buhari ṣe lasiko to wa ni ipo aarẹ lo jẹ manigbagbe.

Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed ti sọrọ sita lori ipapoda aarẹ ana.

Ninu ọrọ rẹ to gbe sori opo ayelujara rẹ, Mohammed ni olori gidi ni Buhari, to fi gbogbo ọkan sin orilẹede Naijiria.

"Ipa ti Buhari ko si idagbasoke orilẹede yii ni ko ṣe fọwọ rọ sẹyin rara."

O wa gba ladura pe ki Ọlọrun tẹ Buhari si afẹfẹ rere.

Ọga agba fun ajọ World Trade Organization (WTO), Ngozi Okonjo-Iweala, ni ko pẹ ti oun fi atẹjisẹ ransẹ si Buhari pe ko ṣe ara giri ni oun gbọ pe o ti jade laye.

Ooni, Iweala, naa daro Buhari

Okonjo-Iweala ṣapejuwe iroyin ipapoda naa gẹgẹ bii ohun to yani lẹnu, to si gba omije loju ẹni pẹlu.

"N ko gbagbọ. Mi o mọ pe o rẹ Aarẹ HE President Buhari bayẹn, isẹju diẹ sẹyin ni mo fi atẹjisẹ ransẹ pe ki ajinde de ba ara rẹ ni mo gbọ pe o ti ku," o sọ loju opo X rẹ.

Arole Oduduwa Olofin Adimula, Ooni ti ilu Ile Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, CFR, Ojaja II, ṣapejuwe iroyin nipa ipapode Aarẹ Buhari gẹgẹ bii eyi to ba ni lojiji.

Ooni ni igbesi aye Buhari lo jẹ eyi to da yatọ sinu itan orilẹede Naijiria, ti iku rẹ si fi opin si igbeaye to sọwọn.

Ooni ni igba ti oun foju kan Aarẹ ana kẹyin, alaafia ni o oun ba ṣugbọn iku jẹ nnkan ti ko si ẹnikẹni to mọ idi rẹ.

"Lati oju ogun gẹgẹ bii olori si Aarẹ orilẹede Naijiria, Buhari jẹ ọkunrin kan to lo gbogbo agbara rẹ si ọna ilọsiwaju orilẹede Naijiria."

Bakan naa, oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi tib a awọn mọlẹbi oloogbe kẹdun, to si ṣapejuwe iku Buhari gẹgẹ bii eyi to ajalu nla fun orilẹede Naijiria.

O ṣapejuwe Oloogbe naa gẹgẹ bii ẹni to fi ara rẹ sipo olori, to si nifẹ orilẹede Naijiria.

"Mo ba iyawo, awọn ọmọ, mọlẹbi ati gbogbo eeyan orilẹede Naijiria kẹdun lori iku Aarẹ Buhari.

"Mo gba ni adura ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ ree."