You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
O ni oku Aarẹ ana, Muhammadu Buhari yoo balẹ si Naijiria lati ilẹ Gẹẹsi
Igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima atawọn eekan mii ti lọ si London lati gbe oku rẹ wale
Buhari yoo wọ kaa ilẹ sun lonii ti oku rẹ ba de Naijiria ṣaaju aago mẹfa irọlẹ, bii bẹẹ kọ o d'ọla
Ana ọjọ Aiku ni Buhari dagbere faye nile iwosan kan niluu London lẹyin aisan ranpe
_______________________________________________
Ipade ti n lọ lọwọ ni aafin Awujale ti ilẹ Ijebu, Ọba Sikiru Kayode Adetona, lori bi eto isinku rẹ yoo ṣe waye
Alẹ ọjọ Aiku ni iroyin gbode pe kabiese ti waja lẹni ọdun mọkanlelaadọrun
A gbọ pe lẹyin ti wọn ba ti kirun si ara oloogbe naa tan ni yoo wọ kaa ilẹ sun nirọlẹ oni
_________________________________________________
Lorilẹede Cameroon
Aarẹ Pual Biya ti kede pe oun yoo dije du ipo Aarẹ fun saa kẹjọ lẹni ọdun mejilelaadọrun
Biya ko tii padanu idibo kankan lati ọdun 1982 to ti gori alefa
To ba tun bori ibo yii, yoo din diẹ lẹni ọgọrun ọdun nigba ti saa rẹ yoo fi pari
Ti ẹ ba fẹ mọ ẹkunrẹrẹ