Àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣesí ààrẹ Buhari tó dá awuyewuye sílẹ̀ lásìkò ìjọba rẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ariṣe ni arika, arika si ni baba iregun; ohun ti a ba ṣe lonii itan ni yoo da bo dọla.

Bi orilẹede Naijiria ti n ṣe idaro aarẹ ana, Muhammadu Buhari, to jade laye lọjọ Aiku ọjọ kẹtala oṣu Keje, ọpọ eeyan lo ti n ṣe iranti awọn ọrọ ati iṣesi rẹ to da awuyewuye silẹ lasiko ijọba rẹ.

Ojo ti n pa igun bọ ọjọ tipẹ lọrọ Buhari jẹ pẹlu awọn nnkan to ti ṣe tabi awọn ọrọ to ti sọ sẹyin eyi to da awuyewuye silẹ.

Ti ẹ o ba gbagbe, Buhari kọkọ ṣe olori ologun orilẹede Naijiria laarin ọdun 1983 si 1985 ki o to di aarẹ alagbada ti araalu dibo yan lọdun 2015.

Saa meji ọtọọtọ ni Buhari lo lori oye gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria laarin ọdun 2015 si ọdun 2023.

Laarin ọdun meji ti Buhari fi jẹ olori ologun Naijiria ati ọdun mẹjọ ti o fi jẹ aarẹ orilẹede Naijiria, a ri ninu awọn nnkan to ṣe tabi ọrọ to sọ tawọn araalu dunnu si.

Bakan naa laa ri awọn asiko ti araalu koro oju, yala si nnkan ti aarẹ ṣe tabi eleyi ti o kọ lati ṣe.

Wọnyii ni awọn ọrọ ati iṣeṣi Buhari to da awuyewuye silẹ lasiko ijọba rẹ gẹgẹ bii olori ologun ati aarẹ orilẹede Naijiria:

Ifilọlẹ eto WAI

Lara awọn nnkan ti ọpọ ọmọ Naijiria yoo maa fi ṣe iranti Buhari ni eto WAI to ni ṣe pẹlu igbogun ti iwa ibajẹ lawujọ ti o ṣe agbekalẹ rẹ.

Eto yii ti Buhari ṣe ifilọlẹ rẹ logunjọ oṣu Kẹfa ọdun 1984 lasiko ijọba ologun rẹ lo mu un ni dandan fawọn ọmọ Naijiria lati maa to ti wọn ba fẹ ra nnkan ni gbangba ti ero ti pọ.

Ọpọ eeyan lo maa n ri iya he ti wọn ba pẹ debi iṣẹ nigba naa, bakan naa ni awọn araalu gbọdọ bọwọ fun asia orilẹede Naijiria labẹ eto WAI.

Labẹ eto yii, araalu gbọdọ gba ile gba ita lasiko naa, bi bẹẹ kọọ, awọn agbofinro yoo fọwọ ṣinkun ofin mu wọn.

Ofin ologun 'decree 4' to sọ ọpọ akọroyin dero atimọle

Ni ọjọ kinni oṣu Kinni ọdun 1984 ni ijọba ologun Buhari ṣe agbekalẹ ofin ologun ti wọn n pe ni ''decree 4.''

Ofin naa sọ pe iwa ọdaran ni akọroyin tabi ileeṣẹ iroyin to ba gbe iroyin kankan to tako ijọba ologun Naijiria hu.

Ijọba ologun Buhari fọwọ ofin mawọn akọroyin to n ṣiṣẹ pẹlu iwe iroyin Guardian, Tunde Thompson ati Nduka Irabor lori ẹsun pe wọn tapa si ofin naa.

Awọn akọroyin mejeeji naa si fi ẹwọn jura nigba naa lọhun.

Ọpọ awọn akọroyin mii yatọ sawọn meji yii ni ijọba ologun ju si atimọle nigba naa.

Buhari gbogun ti oogun oloro

Buhari ṣe ifilọlẹ eto kan lati gbogun ti lilo oogun oloro lọdun 2021 ni saa keji ijọba rẹ gẹgẹ bi aarẹ Naijiria.

Eto yii ni ajọ NDLEA to n gbogun ti oogun oloro n lo lati kilọ fun araalu lori ewu to wa ninu lilo oogun oloro.

Buhari sọ nigba naa wi pe oogun oloro lewu ju awọn to n gbe sunmọmi lọ tori o le pa iran bii mẹta run.

Ajọ oniroyin NAN sọ pe ifilọlẹ eto yii wa ni ibamu pẹlu ayajọ ikilọ ti ajọ UN n ṣe tako lilo oogun oloro lati le daabo bawọn eeyan.

Buhari fikun ọrọ rẹ lasiko naa wi pe iṣẹ gbogbo araalu ni lati gbogun lilo ati kata-kara oogun oloro.

Buhari na aṣofin ni paṣan oju lasiko agbekalẹ abadofin 2019

Iṣẹlẹ yi kii ṣe pe aarẹ sọrọ si eeyan kan tabi araalu, aisọrọ aarẹ gaan nipa pe o na eeyan kan ni pasan oju lo mu ki ayelujara gbina.

Lasiko ti aarẹ wa si iwaju ile aṣofin Naijiria ni ọrọ yi ṣẹlẹ.

Aarẹ n ka awọn ohun to sọ pe ijọba rẹ ṣe laṣeyọri ṣugbọon niṣe ni aṣofin kan n pariwo ti ọrọ rẹ si n bo ti aarẹ mọlẹ.

Ninu ọrọ yi tawọn araalu n wo lori amohunmaworan aṣofin naa n pariwo pe ko si ootọ ninu ọrọ ti aarẹ n sọ.

Kaka ki aarẹ fun lesi, o yi oju si onitọun to si na ni pasan oju.

Pasan yi lawọn ọmọ Naijiria ri to si mu iriwisi ọtọọtọ wa.

Iyipada owo naira

Bi eeyan ba beere lọwọ ọmọ Naijiria mẹwaa nipa ohun ti wọn yoo ranti nipa ijọba aarẹ Buhari, o daju pe pupọ NI yoo mẹnu ba eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ.

Eleyi ti yoo ṣi wa lọkan wọn fọjọ pipẹ gẹgẹ bi iṣẹlẹ manigbagbe ni ọrọ owo Naira ti ijọba lawọn ṣe iyipada rẹ.

Ọkẹ aimọye oniṣowo ati aladani lo kerora lasiko eto yi to si mu inira ba ogunlọgọ ọmọ Naijiria to gbẹmi le ipese owo fun lilo ojojumọ.

Akẹkọọ kan ni fasiti Abuja to ba BBC sọrọ fesi bayi pe''Arakunrin yẹn ba awọn iṣe owo kekeeke ta n ṣe jẹ.''

Awọn akẹkọọ nikan kọ, ati oniṣwo obi, arugbo, ọmọde ati agbalagba gbogbo eeyan lo mọ riri inira iyipada owo yi

Buhari fofin de Twitter

Ninu awọn nkan tawọn ọmọ Naijiria sọ ero ọkan wọn si lasiko ijọba Aarẹ Buhari ni igba to fofin de oju opo Twitter ati igba to gbẹsẹ kuro lori fifofin de oju opo naa.

Ka kọkọ sọrọ nipa igba to fofin de.

Fifi ofin fde oju opo Twitter lati ọwọ ijọba Naijiria ko ṣẹyin bi oju opo naa ṣẹ yọ ọrọ aarẹ kuro loju opo naa.

Ijọba gbẹsan pada awọn naa si fofin de oju opo Twitter lariwo ba sọ.

Ati awọn ọdọ ati ajafẹtọmọniyan gbogbo wọn ni wọn bẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba Naijiria yi .

Ọpọ ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi iwa ijọba amunisin ṣugbọn ijọba ko yẹ ko gbo titi ti ọgọrun ọjọ re kọja daada lori ọrọ yi.

Asẹyinwa aṣẹyinbọ, ijọba pada gba lati tu oju opo yi silẹ ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiria ni ko ni gbagbe inira ti igbesẹ yi mu ba awọn araalu kan.

Buhari ṣe ifilọlẹ ọkọ reluwee igbalode

Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Goodluck Jonathan lo bẹrẹ eto irinajo ọkọ ojuurin igbalode, ijọba Buhari lo pari akanṣe iṣẹ naa ti o si ṣe ifilọlẹ rẹ.

Lẹyin ifilọlẹ eto yii lawọn araalu ni anfaani lati maa wọ reluwee lati ilu kan si omiran.

Ọpọ ni ko wọ ọkọ mọ lati ilu Eko si Ibadan lati igba ti ijọba Buhari ti ṣe ifilọlẹ ọkọ reluwee pada.

Bakan naa ni ọpọ eeyan yan wiwọ ọkọ reluwee lati ilu Abuja si Kaduna laayo, dipo ki wọn wọ ọkọ.

Kaakiri Naijiria lawọn eeyan ti lanfaani lati maa wọ reluwee lati ilu kan si omiran bayii.

Araalu binu si Buhari fun ipa rẹ lori iwọde EndSARS

Lara nnkan manigbagbe ti Buhari ṣe lasiko ijọba rẹ ti ọpọ ọmọ Naijiria ko le gbagbe ni ipa ti o ko lori ọrọ ifẹhonuhan awọn ọdọ tako iwa ipa awọn ọlọpaa SARS si araalu.

Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọdọ lo bọ soju titi ni Lekki TollGate niluu Eko loṣu Kẹwaa ọdun 2020 lati ṣe iwọde tako iwa ipa awọn ọlọpaa SARS yii si araalu.

Buhari kọkọ fofin de awọn ọlọpaa SARS lẹyin ti iwọde awọn ọdọ n gbona janjan.

Amọ, nigba ti iwọde naa n lagbara sii tawọn ọdọ si n beere fun iṣejọba to dara ni Aarẹ Buhari paṣẹ pe kawọn agbofinro to fi mọ awọn sọja lọ tako awọn oluwọde naa.

Bayii lawọn sọja ṣina ibọn fawọn to n ṣe iwọde ni Lekki Tollgate, nibi ti awọn ẹgbẹ ajafẹtọọ ti sọ pe ko din eeyan mejila to ku.

Ohun to bi ọpọ eeyan ninu ni pe Aarẹ Buhari ko sọ nipa awọn sọja to yinbọn sawọn oluwọde nigba to n ba araalu sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

Ni ṣe ni aarẹ kilọ fawọn oluwọde pe ki wọn ma ṣe nnkan to le ṣakoba fun eto abo Naijiria.