You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Buhari wọ káà ilẹ̀ sùn, àwọn ológun àti èèkàn ìlú ṣe ẹyẹ̀ ìkẹyìn fún un
Awa aye ma lọ o si, gbogbo wa ni a jẹ gbese iku.
Ibanujẹ ba gbogbo ọmọ ilu Daura nipinlẹ Katsina nigba ti wọn gbe ọmọ wọn, Muhammadu Buhari, ẹni to ti fi gba kan jẹ Aarẹ ologun ati aarẹ ti a dibo yan lorilẹede Naijiria, wọ ilu naa
Ki I ṣe igba akọkọ ree ti Buhari yoo wa si ilu rẹ ṣugbọn lasiko yii, wọn gbe wọle lai si ẹmi lara.
Ni dede aago mẹfa ku isẹju marun un ni wọn gbe Aarẹ ana, ẹni ọdun mejilelọgọrin wọ kaa ilẹ niwaju awọn iyawo, ọmọ, mọlẹbi, ara ati ọrẹ, pe o di gba.
Aarẹ Buhari lo ọdun mẹsan an ati oṣu mẹjọ ni ijọba, eyi to jẹ apapọ ọdun to fi tukọ orilẹede Naijiria, gẹgẹ bii ologun ati aarẹ ti a dibo yan, eyi to sọ di olori to pẹ ju ninu itan orilẹede Naijiria.
Ọpọ awọn eeyan lo peju sibi eto isinku, lara wọn ni ati ri iyawo oloogbe, Aisha Buhari, Aarẹ orilẹede Naijiria, Aarẹ Bola Tinubu; igbekeji rẹ, Kashim Shettima; igbekeji Buhari fun ọdun mẹjọ, Yemi Osinbajo; igbakeji aarẹ nigba kan ri Atiku Abubakar; oniṣowo, Aliko Dangote; awọn gomina ati gomina tẹlẹ, minisita, lọbalọba, olori ẹṣin ati awon mii.
Saaju eto isinku, Tinubu tẹwọgba oku aarẹ ana ni paapa ofurufu Katsina kete to de lati ilu London
Ààrẹ Bola Tinubu ti tẹ́wọ́ gba òkú Muhammadu Buhari ní Katsina
Aarẹ orilẹede Naijiria Bola Tinubu ti tẹwọgba oku aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lẹyin to balẹ si ipinlẹ Katsina.
Papakọ ofurufu Umaru Mua Yar'adua ni Tinubu ti gba oku naa, ki wọn to morile ilu Daura, nibi ti eto isinku yoo ti waye.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹtala oṣu Keje ni aarẹ ana padanu ẹmi rẹ niluu London lẹyin to ṣe aisan.
Ọpọ olori orilẹede, gomina ipinlẹ ati awọn oloṣelu lo peju si paapa ofurufu lasiko ti wọn gbe oku aarẹ ana de
Rotimi Amaechi, Remi Tinubu àti àwọn èèkàn ìlú tó ti wà nílùú Daura
Iyawo aarẹ orilẹede Naijiria, Oluremi Tinubu ti balẹ si ipinlẹ Katsina fun eto isinku Aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari.
Tinubu lo kọwọrin pẹlu iyawo olori ile igbimọ aṣofin kekere, Fatimah Abbas; iyawo igbakeji olori ile igbimọ aṣofin, Laila Barau; ati iyawo oludamọran si aarẹ lori eto aabo, Zarah Ribadu.
Bakan naa minisita tẹlẹ fun eto irinna, Rotimi Amaechi wa lara awọn eeyan to to kọkọ de si ilu Daura nipinlẹ Katsina.
Rotimi Amaechi de si ilu naa pẹlu aṣọ oye to jẹ niluu Daura.
Báyìí ni ètò ìsìnkú Buhari yóò ṣe lọ lónìí
Gomina ipinlẹ Katsina, Malam Dikko Radda ti kede bi eto isinku Aarẹ ana lorilẹede Naijiria to di oloogbe, Muhammadu Buhari yoo ṣe waye.
Buhari jade laye niluu London lẹyin aisan ranpẹ to koju.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Gomina Radda ni lẹyin ọpọ ijiroro pẹlu mọlẹbi ati awọn eeyan to sumọ oloogbe, wọn pinnu lati gbe oku aarẹ wọle si ipinlẹ Katsina ni ọjọ kẹẹdogun oṣu Keje, ọdun 2025 ni deede aago mejila.
O fikun pe eto isinku naa yoo waye niluu Daura, tii ṣe ilu abinibi aarẹ Buhari ni deede aago meji ọsan.
Bakan naa ni Gomina Radda ba awọn mọlẹbi ati araalu nipinlẹ Katsina kẹdun lori iku aarẹ ana, to si gba a ladura pe ki Ọlọrun duro ti wọn.
"A gba adura si Ọlọrun ọba Allah pe ko fi Aljannatul Firdaus jinki oloogbe.
"Mo tun ba Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu kẹdun lori iṣẹlẹ yii ki Ọlọrun duro ti orilẹede Naijiria lasiko yii."
Ijọba ipinlẹ Katsina ni awọn yoo siṣẹ papọ pẹlu ijọba apapọ ati mọlẹbi lati ri pe eto isinku naa waye ni ilana to bu ọla fun oloogbe to jẹ aarẹ ana lorilẹede Naijiria.
Igbimọ ti yoo ṣakoso ẹyẹ ikẹyin Buhari
Ẹwẹ, Aarẹ Bola tinu ti kede orukọ awọn eeyan ti yoo wa ninu igbimọ kan ti yoo bojuto bi gbogbo ayẹyẹ ikẹyin fun Buhari yoo ṣe lọ.
Igbimọ naa, ti akọwe ijọba apapọ, George Akume n dari ni yoo jiroro ti yoo ṣakoso bi eti isinku ati ẹyẹ ikẹyin Buhari yoo ṣe waye.
Lara awọn ọmọ igbimọ naa ni:
- Minisita eto iṣuna
- Minisita eto abo
- Minisita fun eto iroyin
- Minisita fun ọrọ iṣẹ
- Minisita fun ọrọ abẹle
- Minisita fun FCT
- Minisita fun ile kikọ ati idagbasoke agbegbe
- Minisita abẹle fun eto ilera
- Minisita fun ọrọ aṣa
- Olubadamọran pataki fun Aarẹ lori eto abo
- Olubadamọran agba fun Aarẹ lori ojuṣe atawọn ọrọ mii
- Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa
- Ọga agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, atawọn mii
Lati bu iyi fun oloogbe, Aarẹ ti paṣẹ ki wọn gbe iwe ibanikẹdun siwaju bogbo ọọfisi ijọba apapọ nibi ti awọn eeyan yoo ti maa kọ ọrọ ikẹyin wọn fun Buhari.
Ijọba apapọ kede ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ fun eto isinku Buhari
Yatọ si ikede ọjọ meje fun idaro, Ijọba apapọ kede ọjọ kẹdogun oṣu keje ọdun 2025 gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ fun awọn oṣiṣẹ fun eto isinku aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari GCFR.
Eyi lo wa ninu atẹjade kan ti ministi fun ọrọ abẹle lorilẹede Naijiria, Dr, Olubunmi Tunji-Ojo fi sita, lẹyin ibuwọlu aarẹ orilẹede Naijiria, Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, GCFR.
Minisita ni ikede yii lo waye lati bu ọla fun ipa ti aarẹ ana ko fun ilọsiwaju orilẹede Naijiria lati igba to ti jẹ olori ijọba ologun.
"Aarẹ Muhammadu Buhari sin Naijiria tọkantọkan, pelu iwa ọmọluabi ati wiwa isọkan orilẹede Naijiria.
"Ọjọ isinmi yii yoo pese anfani fun awọn araalu lati se iranti igbesi aye aarẹ to di oloogbe," Minisita ṣalaye.
O rọ araalu lati lo lasiko naa lati fi bu ọla ikẹyin fun igbesi aye Aarẹ ana to nifẹ alaafia ilu, to n siṣẹ tọ ilọsiwaju orilẹede Naijiria.
Ta a ni Muhammadu Buhari?
Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Muhammadu Buhari, to ku lẹni ọdun mejilelọgọrin, ti figba kan ri jẹ olori ologun orilẹede Naijiria ki o to di aarẹ alagbada lẹyin to dupo aarẹ ninu idibo gbogbogbo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.
Amọ, ọpọ ọmọ Naijiria ni ko gbagbọ wi pe Buhari mu awọn ileri to ṣe ṣẹ lasiko to wa nipo aarẹ.
Bi Buhari ṣe maa n ṣe yatọ sawọn olosẹlu yooku, o maa n saba duro lori ọwọ rẹ ni nigba aye rẹ.
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo mọ ọn gẹgẹ bi olootọ eeyan, eyi to ṣọwọn laarin awọn oloṣelu Naijiria.
Lẹyin to dupo aarẹ fun igba mẹta ọtọọtọ ti ko wọle, Buhari pada wọle ibo aarẹ ọdun 2015, o si di oludije sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu alatako akọkọ ti yoo la aarẹ to wa lori oye mọlẹ ninu eto idibo ni Naijiria.