You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ikùn ni mò ń gbà ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ àti isó nítorí jẹjẹrẹ tó mú mi- Tobiloba Oluwasina
Aarun to n bẹ lode aaye ko lonka tan, ṣugbọn ọtọ ni ti jẹjẹrẹ ti a mọ si Cancer, to pin si oriṣiriṣi.
Idi ni pe o fẹrẹ ma si ẹya ara ti aarun naa ko le mu , oriṣiiriṣii rẹ lo wa, ko si sẹni ti ko le mu.
Jẹjẹrẹ olorukọ nla kan lo kọlu ọdọmọbinrin ẹni ọdun mọkanlelogun (21), Oluwasina Tobiloba Elizabeth, to si sọ ọ di ẹni ti ko le ṣe igbọnsẹ loju idi bii awọn eeyan yooku mọ, to jẹ inu rẹ lo n gba ṣe igbọnsẹ sita.
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Tobiloba?
Nigba to n ṣalaye pẹlu omije loju fun BBC, Tobiloba sọ pe:
'' Nigba ti dokita kọkọ sọ fun mi pe inu ni ma a ti maa ṣegbọnsẹ, ko fi gbogbo ara ṣalaye naa fun mi.
''Oṣu Kẹta ọdun 2022 ni wọn ṣawari jẹjẹrẹ ti wọn n pe ni Rectal Cancer lara mi (Ohun naa ni wọn tun n pe ni Signet Ring Adenocarinoma).
Jẹjẹrẹ yii lo maa n yọ ifun nla to rọ mọ igbọnsẹ ṣiṣẹ lẹnu.
''Iṣẹ abẹ ni dokita kọkọ ṣe fun mi nigba naa, o si sọ fun mi pe inu ni maa maa gba ṣe igbọnsẹ .
''Mo wo ara mi wo, mo si n sọ funra mi pe o ti tan. Abi nigba ti eeyan ko ba le ṣegbọnsẹ loju idi mọ, to jẹ inu lo ku ti yoo ti maa ti ẹgbin jade, ki lo tun ku.
''Itiju ati idẹyẹsi ni mo bẹrẹ si i koju latigba naa, nitori mi o le jade bo ṣe wu mi saarin awọn eeyan, apo igbọnsẹ ti mo n gbe sinu ko jẹ.
''Igba kan wa ti mo tilẹ fẹẹ pa ara mi lati fopin si gbogbo ẹ, awọn ẹgbẹ mi ti wọ ileewe giga, emi wa nile. Tobiloba sọ, pẹlu omije loju.
''Jẹjẹrẹ náà tóbi débi pé wọn ò kọ́kọ́ lè fi iṣẹ́-abẹ gbé e jáde''
Ni itẹsiwaju alaye rẹ nipa jẹjẹrẹ yii, Tobiloba sọ pe awọn dokita ko kọkọ le ṣe iṣẹ abẹ fun oun lati mu jẹjẹrẹ ọhun kuro.
''Lasiko iṣẹ abẹ akọkọ ti wọn ṣe fun mi, awọn dokita ko le gbe jẹjẹrẹ yẹn jade, o tobi gan-an.
Jẹjẹrẹ naa tobi debi pe, o ti so mọ ọpọ awọn ẹya ara mi miran, o si le pa mi to ba wọnu ara mi lọ. ''Nigba naa ni awọn dokita gbe ẹrọ kan jade ti wọn fi ṣe ohun ti wọn n pe ni ' Colostomy', fun mi.''
Colostomy yii jẹ iṣẹ abẹ ti wọn fi maa n la ọna de ifun nla, lati inu eeyan.
Gẹgẹ bi alaye ile-ẹkọ iwadii ijinlẹ John Hopkins, Colostomy yii le wa fun igba diẹ, o si le jẹ eyi ti yoo wa titi lai, fun ẹni to ba tọ si.
Eyi ti yoo wa titi lai ni wọn ṣe fun Oluwasina Tobiloba Elizabeth.
Ohun ojú rí
Oṣu Kẹrin ọdun 2022 ni Tobiloba bẹrẹ itọju ti wọn maa n fun awọn to ba ni jẹjẹrẹ ti a mọ si 'Chemotherapy''.
O ni oun ṣe ipele mẹfa akọkọ to yẹ koun ṣe, ṣugbọn ko si iyatọ kankan lara oun.
Ọmọbinrin naa loun tun gba Chemo mẹfa miran lẹyin eyi, sibẹ naa, ko si iyatọ.
O ni lẹyin eyi loun tun lọ fun iṣẹ abẹ kẹta loṣu Keji ọdun 2024.
Igba kẹta yii ni awọn dokita ṣẹṣe ri jẹjẹrẹ naa gbe jade, ṣugbọn wọn ko ri Colostomy ti wọn ṣe si furọ rẹ mu kuro, gbere ni.
Tobi sọ pe wọn di oju furọ oun pa nigba ti wọn n ṣe Colostomy naa ni.
''Nigba ti wọn sọ fun mi pe mi o ni i le ṣegbọnsẹ lati furọ mi mọ, o ba mi lọkan jẹ gan-an.
''Ohun to maa n jẹ ki eeyan mọ to ba fẹẹ ṣegbọnsẹ ko ṣiṣẹ mọ lara mi, wọn ti ge gbogbo ẹ kuro.
''Bi mo ṣe n lo aye mi bayii ni pe ti mo ba ti ji laaarọ, mo maa ṣegbọnsẹ.
''Ma a waa lọ sile igbọnsẹ, ma a lọọ da igbọnsẹ to wa ninu apo ti mo n so mọnu nu, ma a si ti ẹnu apo naa pa''
Tobiloba ni ti oun ko ba ri igbọnsẹ ṣe, oun yoo só, nitori nibi inu oun naa ni iso ti n wa.
''Itiju ti Colostomy mu ba mi niyẹn, mi o le sunmọ awọn eeyan bo ṣe tọ mọ, mo maa n ya ara mi sọtọ ni, nitori mi o ni i fẹ kawọn eeyan mọ pe apo wa ninu mi ti mo n gbe kiri.''
Ni bayii ṣaa, o ni oun ti n gbiyanju lati maa darapọ mọ awọn eeyan.
Kí ni jẹjẹrẹ Rectal adenocarcinoma?
Jẹjẹrẹ to wọpọ ni, ibi ifun ati ọna igbọnsẹ lo maa n yọ lẹnu.
O maa n bẹrẹ lati ibi ẹya ara to n pese nnkan bii ikun nibi furọ, gẹgẹ bi ẹka Cancer Center ṣe sọ.
Kinni kan yoo kọkọ maa wu labala ibi to ti fẹẹ bẹrẹ, o si le pada di jẹjẹrẹ.
Àpẹẹrẹ Rectal adenocarcinoma
*Ikọ ti ki i lọ bọrọ
*Rirẹ ara
*Ki egungun maa ro eeyan
*Ai le mi daadaa
*Ai le jẹun
* Ki oju tabi awọ ara yi pada di awọ ofeefe (yellow)
* Ki ọwọ ati ẹsẹ maa wu
* Ki iyatọ ba iriran tabi bi eeyan ṣe n sọrọ
Awọn to ṣee ṣe ki wọn lugbadi jẹjẹrẹ yii
*Awọn to n mu ọti amuju
*Awọn ti ki i jẹ eso, ewebe ti wọn si waa fẹran lati maa jẹ ẹran pupa.
*Aisan to ni i ṣe pẹlu igbọnsẹ ṣiṣe
*Ajogunba
*Ara asanju
*Ọjọ ori/ agba dida.