Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìṣèjọba Ibrahim Babangida tí ẹnu ń kùn lẹ́yìn tó ṣèwé síta

    • Author, Uche Akolisa
    • Role, BBC News,Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Fun ọpọ ọdun bayii, opọ ọmọ orilẹede Naijiria lo n wa idahun si awọn ibeere ti o fa okunkun ọjọ pipẹ lọwọ ọkunrin kan; Ibrahim Badamasi Babangida.

Ni ọsẹ to kọja, Babangida pese idahun si awọn ibeere naa ninu iwe rẹ, nibi to ti ṣalaye gbogbo ohun to waye lasiko to jẹ olori ijọba ologun fun Naijiria.

Babangida jẹ olori ijọba ologun lati ọdun 1985 si 1993 – ti ọpọ n si pe ni IBB ni ṣapejuwe gẹgẹ bii ẹni to se eto idibo ti mọ ju ni Naijiris ṣugbọn to tun wọgile.

Awọn kan ni ipo ti Naijiria wa lonii ni ipa ọrọ aje bẹrẹ lati asiko iṣejọba Babangida ati pe oun gan an lo bẹrẹ rẹ.

"Gẹgẹ bii olori ijọba ologun, mo gbe ẹbi fun gbogbo igbesẹ yoo waye lasiko ijọba mi," Babangida sọ ninu iwe rẹ, 'A Journey in Service': itan igbesi aye rẹ.

Igba ti Babangida bọ sipo ati diẹ ninu ohun waye?

Ọdun 1983 ni Babangida bọ sipo agbara lẹyin ti iditẹgbajọba lọwọ Aarẹ Shehu Shagari waye, ti Ọgagun Muhammadu Buhari si bọ sipo olori.

Ṣugbọn lẹyin ogun oṣu, Ọgagun Babangida gba agbara lọwọ Buhari ninu iditẹgbajọba miiran, to si di olori ilu. Babangida fẹsun kan iṣejọba Buhari pe o n fa inira.

Ẹwẹ, kudiẹkudiẹ eto ọrọ aje tunbọ tẹsiwaju lasiko iṣejọba Babangida ni ọdun mẹjọ gẹgẹ bii olori, eyi ti awọn kan ni oun lo buru ju. Igbiyanju rẹ lati mu ayipada wa pẹlu eto SAP nipa iranlọwọ IMF ati Banki Agbaye lo ja si pabo.

Lara awọn nnkan ti ijakulẹ ba ni owo naira, ọwọngogo, airiiṣẹ ati kudiẹkudiẹ eto ọrọ aje, eyi to pada fa ọpọ iwọde ati ifẹhonuhan lati ọdọ awọn akẹkọọ ati ẹgbẹ oṣisẹ.

Sibẹsibẹ, iṣejọba naa ni awọn aṣeyọri ti eeyan le tọka si; o paarọ ofin ologun Decree 4 ti ọdun 1984 to fofin de awọn akọroyin lati le kọ iroyin tako ijọba , to si tun faaye gba awọn ileeṣẹ aladani.

Iṣejọba rẹ fun orilẹede Naijiria ni ọpọ iyi lagbaye fun ipa to ko ninu riri daju pe alaafia jọba.

Iṣejọba rẹ lo pari afara Third Mainland Bridge to wa niluu Eko ti iṣejọba Shehu Shagiri bẹrẹ, to si jẹ afara to gun ju ni ilẹ Africa titi wọ ọdun 1996.

Babangida lo da awọn ajọ bii FRSC ati NDLEA silẹ lorilẹede Naijiria.

Idasilẹ ipinlẹ naa ko gbẹyin lasiko iṣejọba Babangida. Lasiko rẹ ni awọn ipinlẹ bii Katsina jade lati Kaduna, Akwa Ibom lati Cross River waye ni ọdun 1987, nigba to ya lo tun buwọlu idasilẹ awọn ipinlẹ bii Abia lati ipinlẹ Imo, Delta, Edo, Enugu, Jigawa, Kebbi, Osun, Taraba, Yobe ati Kogi.

Babangida gbero lati da ijọba pada fun ijọba awaraawa ni ọdun 1990 ṣugbọn o sun si 1993, to si tun wọgile eto idibo naa. Eyi fa ọpọ rogbodiyan, to si jẹ pe oun lo bi ayajọ 'June 12'.

Babangida ni lati kọwe fipo silẹ, to si yan aarẹ fidiẹ, Ernest Shonekan.

Awọn amoye ṣapejuwe wiwọgile eto idibo June 12 gẹgẹ bii ohun to ṣokunfa ọpọ ifasẹyin fun orilẹede Naijiria titi di oni.

Bakan naa ni asiko iṣejọba Babangida jẹ eyi to nira pupọ fun awọn akọroyin. Ọpọ ileeṣẹ iwe-iroyin lo di titi pa, ti awọn akọroyin si koju idunkoko.

Iṣukupani Dele Giwa, ọtẹlẹmuyẹ akọroyin pẹlu lẹta to ni ado-oloro ninu ni ọdun 1986 waye lasiko iṣejọba Babangida.

"Ohun to ṣekupa Giwa ati awọn iṣekupa miiran jẹ ohun ti wọn ko ri yanju fun ọpọ ọdun. Mo si lero pe wọn yoo ri yanju loju aye wa tabi lẹyin ti a ba lọ," Babangida sọ ninu iwe naa lati ṣalaye pe oun ko mọ ohunkohun nipa rẹ.