You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ó ṣeéṣe kí gbogbo ọmọ Naijiria má le kàn síra wọn lórí fóònù mọ́ - ATCON
Ẹgbẹ awọn ileeṣẹ to ri si ibaraẹnisọ lorilẹede Naijiria ti ke gbajari sita lori airi epo disu ra nitori bi awọn awak tanka epo se da iṣẹ silẹ.
Aarẹ ATCON, Tony Emoekpere lo kede eyi ninu atẹjade kan to buwọlu fun awọn akọroyin pe airi epo disu ra n se akoba nla fun awọn ileeṣẹ to n risi nẹtiwọki, to si ti n de bi pe wọn yoo ko gba wọle, ti eyi si n dun koko mọ ọpọ awọn eeyan to n lo oju opo ayelujara .
"Iyanṣẹlodi yii, ti awọn awakọ epo gunle yii ti da ọpọ nnkan duro bayii," Emoekpere ṣalaye.
Emoekpere ni ti ijọba ko ba tete gbe igbesẹ to yẹ ni kiakia, o ṣeeṣe ki oju opo ayelujara pana, ti ọpọ eeyan, ileeṣẹ ko si ni ni, anfaani lati lo oju opo ayelujara.
ATCON wa kesi Gomina ipinlẹ Eko ati Ogun lati da si ọrọ to wa ni ilẹ nipa wiwa ọna ti epo disu yoo fi wa fun rira fun awọn awọn ileeṣẹ to n risi oju opo ayelujara, ti eyi yoo si dena de airi oju opo naa lo.
O ni eyi ki i se fun oju opo ayelujara nikan, o ni yoo ran iṣẹlẹ pajawiri, to si tun le se akoba nla fun eto ọrọ aje.
ATCON wa tun rọ awọn eleto aabo ati ẹgbẹ alagbata epo lorilẹede Naijiria lati yanju aawọ to ba wa laarin wọn, ki o ma se akoba fun eto ọrọ aje Naijiria.
Laipẹ yii ni owo ipe lori foonu ati data lọ soke ni Naijiria lẹyin ti ajọ NCC to n ri si eto ibaraẹnisọrọ ni Naijiria ti buwọlu aba awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ lati ṣe afikun owo tariifu tawọn onibaara wọn n san.
Ida 50% ni awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ yoo fi ṣe afikun owo ipe ati data naa.
Ajọ NCC ṣalaye pe afikun ida 50% yoo waye nitori bi gbogbo nnkan ṣe gbowo lori lẹkun ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ.