Ìdí tí a fi dìtẹ̀ gbàjọba Buhari lọ́dún 1985 - IBB sàlàyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oniruuru iṣẹlẹ to ti ṣẹlẹ siwaju ni olori orilẹede Naijiria tẹlẹri, Ajagun fẹyinti Ibrahim Babangida sọ nipa wọn ninu iwe to kọ nipa ara rẹ to pe ni ""Irinajo lẹnu iṣẹ" (A journey in Service) eyi to ṣe ifilọlẹ rẹ lọsẹ to kọja niluu Abuja.

Ẹ o ranti pe ninu iwe naa lo ti kede pe oloogbeMKO Abiola lo gbegba oroke ninu izsdibo June 12, 1993, to si ti dohun ti awọn eeyan n ṣe atupalẹ ọrọ naa kiri bayii.

Lara awọn nnkan mii ti olori orilẹede Naijiria tẹlẹri ri sọrọ le lori ninu iwe ọhun ni alaye rẹ lori idi ti o fi ditẹ gbajọba ologun Muhammadu Buhari lọdun 1985.

Babangida sọ ninu iwe to pe akọle rẹ ni "Irinajo lẹnu iṣẹ" pe Buhari nikan lo n da ijọba ṣe.

Ti ẹ o ba gbagbe, Buhari wa lara awọn olori ologun to diẹ gbajọba Aarẹ Shehu Shagari ti araalu dibo yan lọdun 1983.

Amọ, lẹyin ogoji ọdun ti Babangida doju ijọba Buhari ati igbakeji rẹ, Babatunde Idiagbon bolẹ, Babangida to ṣe ijọba ologun ni Naijiria fun ọdun mẹjọ sọ pe Buhari ati Idiagbon n ṣe bi ẹni pe awọn lo gbọn julọ l'awọn ṣe gba ijọba wọn.

Babangida ni Buhari tako araalu at'awọn ologun bii tiẹ gan an lasiko ijọba rẹ.

"O ṣe pataki lati ṣe ayipada ijọba nigba naa tori bi araalu ṣe n kọminu nipa ọjọ iwaju Naijiria labẹ iṣejọba ologun Buhari ati Idiagbon.

Niṣe ni mo maa n ro o pe bawo ni a ṣe di ibi ti a wa labẹ ijọba Buhari.

Nigba ti yoo fi di ibẹrẹ ọdun 1985, ìbẹru bojo ti gbakẹ kan ni Naijiria.

O ti wa han gbángba pe igbesẹ ologun lati dìtẹ gbajọba lọdun 1983 ko kẹsẹjari pẹlu bi nnkan ṣe n lọ nigba naa.

Ipinya ti wa ninu iṣẹ ologun, mo si gbagbọ pe ti ipinya aarin awọn ologun ba tẹsiwaju, yoo pada ṣakoba fun orilẹede Naijiria bakan naa," Babangida ṣalaye.

Babangida ni Buhari ati Idiagbon ti ya ara wọn sọtọ ni ileeṣẹ ologun, bakan naa si ijọba wọn n fi ẹtọ ọmọnìyàn dun araalu lera lera.