Amotekun on Osun election: Tí a kò bá ti kò ìbọn, kùmọ̀, àdá lọ ilé ìdìbò, ẹ má gbé 'yẹn wá o! Ojú l'alákàn fi ń ṣọ́ orí
"Bí ọmọ ìjọ Kátólìkì bá mú "rosery" dání lọ dìbò, àbí Mùsùlùmí tó fa tẹ́síbìyù lọ́wọ́, ẹni tó mú ìrọ́kẹ́ Ifá lọ́wọ́, ṣe ẹ̀ṣẹ̀ wà níbẹ̀ ni?"
Alakoso ikọ Amotekun ni ipinlẹ Osun, Amitolu Shittu ti ba BBC Yoruba sọrọ.
Amitolu ṣalaye iroyin to tan kaakiri pe wọn paṣẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ki wọn dira pẹlu oogun ibilẹ lọ sibi idibo to n waye.
Ṣaaju ni aṣẹ ti jade lati ile ẹjọ pe Òṣìṣẹ́ ikọ̀ Amotekun kankan kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ níbi ètò ìbò gomina Osun- Ilé ẹjọ́

Amitolu ni ki ẹnikẹni ma wadi awọn rara toripe o yẹ ki wọn gbọ ara wọn ye nilẹ Yoruba tori nkan to n jẹ Amotekun tẹlẹ naa ninu Sayẹnsi naa ni Amotekun n jẹ o. "Ko nibọn, ko ladaa, ko laake, ẹ fiilẹ bẹẹ o".
Bakan naa lo ṣalaye pe ejo lọwọ ninu ni ọrọ ti ile ẹjọ ṣe paṣẹ pe ki awọn ma kopa ninu idibo.
O ni agbẹjọro to ni ki wọn yọ oun nipo nigba kan naa lo tun n sọ ọrọ wipe ki awọn ma lọ sibi idibo lọ ran awọnagbofinro lọwọ.