Endsars anniversary: Falz ní kò sí ohun tí yóò yẹ ìwọ́de tí yóò wáyé ní Lekki Toll Gate ní Oct 20

Gbajugbaja olorin takasufe, Folarin Falana,Falz

Ni bayii ti awọn ọmọ Naijiria kan ti n mura lati ṣe iwọde ni iranti ifẹhonuhan EndSARS to waye lọdun 2020, ọpọ eeyan lo ti bẹrẹ si n sọ erongba wọn lori iwọde ọhun.Lara awọn eeyan naa ni gbajugbaja olorin takasufe, Folarin Falana, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Falz.Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kọkọ fi atẹjade kan sita lati ọwọ alukoro rẹ, Adekunle Ajisebutu pe awọn ko ni gba ki ẹnikẹni ṣe iwọde kankan ni iranti iwọde EndSARS.

awọn oluwọde EndSARS

Oríṣun àwòrán, The africa report.com

Falz ti wa sọ pe ariwo ẹnu lasan ni ileeṣẹ ọlọpa n pa nitori ko si ohun ti yoo yẹ iwọde naa.O ni "Awọn were, kọmiṣọna ọlọpaa ni ki a ma jade sita nitori wọn mọ pe ogunjọ oṣu Kẹwaa ti n sumọle.""Wọn ni ki a má jade lọjọ naa, ṣe ori wọn ti daru ni?""Ko si ohun ti wọn ba ṣe tabi irufẹ ẹni ti wọn le jẹ, wọn ko le ni ki a ma ṣe iwọde lọjọ naa."

Iwoyi ọdun to kọja ni awọn ọdọ tu sita ni Naijiria, ti wọn si n ṣe iwọde tako bi awọn agbofinro SARS ṣe n fi iya jẹ awọn araalu lọna aitọ.Iwọde naa lọ daadaa kaakiri apa Iwọ Oorun Naijiria, paapaa niluu Eko ki nnkan to yiwọ ni iloro Lekki Toll Gate.

Wahala bẹ silẹ lẹyin ti awọn ọmọ ogun fi ibọn tu awọn oluwọde naa ka logunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.

Awọn oluwọde nibi iwọde EndSARS kan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Nibẹ ni awọn eeyan kan ti padanu ẹmi wọn ti ọpọ eeyan si farapa lẹyin ti awọn ṣọja dana ibọn ya awọn oluwọde ọhun.Bo tilẹ jẹ pe iwadii ti bẹrẹ, ijọba ipinlẹ Eko si ti san owo gba mabinu fun awọn eeyna kan ti iṣẹlẹ naa kan gbungbun.

Ko tii si ẹnikankan to tii foju wina ofin lori iṣẹlẹ lọhun, eyii to n bi ọpọ ọdọ ninu.

Wayi o,ọpọ iwe pelebe lo ti n lọ kaakiri ori ayelujara Naijiria lori bi iwọde naa yoo ṣe waye.Ni ti ọrọ SARS to jẹ eku ẹda to da gbogbo rogbodiyan naa silẹ, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ko gbero lati da ẹka ọhun pada gẹgẹ bii awọn kan ṣe n ṣe n sọ laarin ilu.