KSA mourns wife's death: Sunny Ade ti kéde ọjọ́ ìsìnkú ìyàwó rẹ̀, Risikat Adegeye, Ó ní ańgẹ́lì òun ló kú

Oríṣun àwòrán, other
Agbaọjẹ akọrin Juju nii King Sunny Ade ti sọrọ nipa iku iyaworẹ, ọmọọba Adejọkẹ Adegẹye ti wọn yoo sinku rẹ lọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Kẹsan .
KSA ṣapejuwe iku Risikat Adegeye gẹgẹ bi eleyi to fọwọ kan mọlẹbi lẹmi ṣugbọn o ni oun dupẹ fun iru igbe aye ti Risikat gbe.
''Mo dupẹ fun Ọlọrun lori gbogbo nkan to ṣẹlẹ nitori gbogbo nkan lo yee ju awa ẹda lọ.Iku Risikat jẹ eyi to dun emi ati mọlẹbi mi''
- Òjó ìyà tó rọ̀ ní Emirates, orí Tottenham ló rọ̀ lé, ànàkáwọ́lérísunkún ni Arsenal nà wọ́n
- Wo ohun tí ọlọ́pàá sọ nípa 'Charlie', ajá tó gé kórópọ̀n akẹ́kọ̀ọ́ fásitì AAUA jẹ l'Ondo
- 'Bola Tinubu ńbọ̀ ní Nàìjíríà láìpẹ́, àmọ́ kò tíì dé'
- 'Eniola Badmus wọ pátá lọ sí ààfin Oba Elegushi, "ọ̀ín" kí ló burú níbẹ̀?'
King Sunny Ade ni Risikat kọja iyawo nikan fun oun.
O ni ''Angẹli mi ni mo si maa n pe ni baby mi.Iyawo ti gbogbo ọkunrin daada ati ọmọ daada gbọdọ ni Risikat jẹ''
Atẹjade lati ọdọ awọn mọlẹbi ni wọn yoo tẹ Risikat safẹfẹ ree lẹyin igba naa ni wọn yoo sin oku rẹ nilu Eko.
Sunny Ade wa fi ọrọ idupẹ ranṣẹ si awọn ọrẹ ati ololufẹ to ti n fi ọrọ ikini ranṣẹ lati igba ti Risikatu ti jade laye.
Risikatu fi igba kan jẹ aṣofin nile aṣofin ipinlẹ Eko.
Ọmọ ọkunrin mẹfa lo bi fun King Sunny Ade ti a si tun gbọ pe o jade laye ni ọjọ kan si ọjọ ayẹyẹ ọjọ ibi Sunny Ade.













