African Eye: Wo Jane Mugo, obìnrin bíi ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ bíi James Bond
Isẹ atọpinpin tabi ọlọfintoto la mọ bii isẹ to wa fun awọn ọkunrin nitori ọpọ ewu to rọ mọ.
Gbogbo ẹni to ba si maa n wo sinima ilẹ okeere ni yoo ranti akikanju ọkunrin kan ti wọn n pe ni James Bond ati ọpọ ewu to maa n la kọja nidi isẹ ọlọfintoto to yan laayo ninu sinima.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu obinrin yii lorilẹede Kenya,m ti orukọ rẹ n jẹ Jane, ẹni ti isesi ati isẹ rẹ fara jọ ti James Bond.
Ọtẹlẹmuyẹ Jane Mugo ni ilumọọka osisẹ atọpinpin aladani to gbajumọ julọ lorilẹede rẹ, ti ẹnu kii si sin lara rẹ.
Jane ni ọkẹ aimọye iwa ọdaran ni oun ti wa ojutu si amọ lọna mii, o maa n se ofin tara rẹ, lọwọ ara rẹ.
Jane maa n lo oniruuru ọna lati sewadi iwa ọdaran, lara rẹ ni amulo ọmọlangidi, taa mọ si Teddy Bear ati aago ara ogiri.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Ìtàn ayé Taiwo Oredein rèé, àgbà òṣèlú tó parí ayé rẹ̀ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
- Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa
- Ó pé ọdún mẹ́rìnlélàádọ̀ta tí Akintola kú, ìdí abájọ ìja rẹ̀ pẹ̀lú Awolowo rè é
Ẹ wa nnkan fidi le lati wo fidio akọni obinrin yii, to n sisẹ akikanju bii ọkunrin, to si n ba ewu rin lai bẹru.


