Ondo election 2020: Irọ́ ni pé ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́wàá korajọ láti fi olùdíje kan sílẹ̀ fún ìbò gómìnà - LP, NRM

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria
"Irọ ni o, ko si n kan to jọ ọ pe, a ti fi ẹgbẹ oṣelu wa silẹ."
Eyi ni esi ti alaga ẹgbẹ oṣelu Labour Party nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Amos Agunloye ati oludije fun ipo gomina, fẹgbẹ oṣelu National Rescue Movement, NRM, Ọgbẹni Funmilayo Ataunoko sọ.
Eyi ni wọn fi n tako iroyin kan to jade sori ayelujara pe, wọn ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mẹjọ miran lati fa oludije kan ṣoṣo silẹ, fun eto idibo gomina ipinlẹ Ondo to n bọ.
Ninu iroyin naa, ti awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan gbe sita ni wọn ti sọ pe, Olugbemi Ogunbameru (SDP) ati Comrade Israel Ayeni (AAC), ti fi ọwọ si iwe adehun, lati yan oludije kan labẹ aburada Conference of INEC Registered Political Parties (CIRPP).

Oríṣun àwòrán, ondostate.gov.ng
Awọn eeyan mii ti wọn tun darukọ pe o se adehun naa ni awọn alaga ẹgbẹ oṣelu bi i Prince Niran Toyin (APGA), Ọgbẹni Olaoluwa Adesanya (APP) ati Oloye Tokunbo Adetoro (ADC).
Bakan naa ni wọn ni Ajibola Falaiye (Accord), Olagookun Peter (NNPP), Felix Funso Oloro (APM), Funmilayo Ataunoko (NRM) ati Amos Agunloye (LP) lọwọ si adehun naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho kàn ń gbé ‘Camera’ lẹ́yìn kiri, kí wọ̀n lè rò pé ó ń jà fún Yorùbá - Gani Adams
- Ẹ lọ ṣí gbogbo ilé ẹ̀kọ́ padà ní Nàíjíríà - Ìjọba àpàpọ̀
- Irọ́ ni o! Ìyàwó Ọ̀ọ̀ni Ogunwusi kò bímọ tuntun
- A kò ṣetán láti fa olùdíje kanṣoṣo kalẹ̀ fún ìbò gómìnà l‘Ondo - Àgbáríjọ ẹgbẹ́ òṣèlú
- Donald Trump àti ìyàwó rẹ́ ti lùgbàdì àrùn CoronaVirus
- Fídíò rèé lórí bí Sunday Igboho ṣe korò ojú sí ìwà ọ̀dàlẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá
- Ìfẹ́ Yorùbá ló mú mi fi ẹ̀mí wéwu láti kojú ajínigbé ní Kishi - Sunday Igboho
Ṣugbọn ninu ọrọ ti wọn ba BBC sọ, Ọgbẹni Amos Agunloye sọ pe irọ ni iroyin naa.
"Ko ṣe e ṣe fun mi lati darapọ mọ ẹgbẹ oselu miran, nigba ti mo ni oludije temi."
Ninu ọrọ ti ẹ naa, oludije fun ẹgbẹ osẹlu NRM Ọgbẹni Funmilayo Ataunoko sọ pe "awọn kan lo n sọ pe a ti gba owo lọwọ ẹgbẹ osẹlu , ṣugbọn irọ ni.
Eyi lo mu ka fi atẹjade sita pe, a ko gba owo lọwọ ẹnikẹni, emi naa fẹ ẹ dije, a si fẹ ẹ jawe olubori ninu idibo to n bọ ni."













