Coronavirus: Wọ́n ti gbé olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹẹsi, Boris Johnson lọ sí wọ́ọ̀dù aláísàn tó lágbára

Boris Johnson, Ọlóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin to tẹ wa lọwọ lo sọ pe, wọn ti gbe olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson lọ si wọọdu itọju aisan to lagbare bayii lẹyin to lugbadi aarun coronavirus.

Boris Johnson laa gbọ pe o sọ fun akọwe ijọba fun ilẹ okeere, Dominic Raab wi pe ko maa ṣoju oun nigba ti oun n gba itọju.

Lati irọlẹ ọjọ Aiku ni Ọgbẹni Johnson ti n gba itọ lẹyin ti covid-19 to wa lara rẹ n ba a finra.

Olotu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson ti di ero ileewosan bayii fun awọn ayẹwo gbogbo to yẹ lẹyin ọjọ mẹwaa ti ayẹwo ti kọkọ fihan pe o ti ko arun Coronavirus.

Coronavirus symptoms: Boris Johnson, Ọlóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì dèrò iléèwòsàn nítorí àrùn Coronavirus

Atẹjade kan lati ileeṣẹ ijọba ilẹ Gẹẹsi ti a mọ si Downing Street ṣalaye pe niaṣalẹ ọjọ Aiku ni wọn gbe lọ si ileewosan kan ni ilu Lọndọn nigba ti o n ṣa afihan aisan naa tofimọ ara gbigbona.

Amọṣa ileeṣẹ ijọba ilẹ Gẹẹsi ṣalaye pe oun ṣi ni akoso ijọba wa ni ikawọ rẹ, bi o tilẹ jẹ wi pe minisita fun ọrọ ilẹ okeere ni ireti wa pe yoo lewaju ipade kan ti yoo waye lori ọrọ arun Coronavirus ni owurọ ọjọ Aje.

Afikun nipa aarun Coronavirus
Coronavirus

Wọn ni igbesẹ itọju lasan ni gẹgẹ bi amọran dokita to n tọju rẹ

Gẹgẹbi akọroyin nipa oṣelu nileeṣẹ BBC, Laura Kuenssberg ṣe sọ, Ọgbẹni Johnson yoo sun orun alẹ ọjọ kan nibẹ lati lee ṣe awọn ayẹwo gbogbo to ba yẹ.

Lati ile rẹ ni olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi naa ti n ṣe iṣẹ rẹ gbogbo lati igba ti ayẹwo ti gbe e jade ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹta pe o ni arun naa.