Fake news: ìmọ̀ràn fáwọn ọmọ Nàìríjíà ṣaájú pínpín ìròyìn- Aṣòfin àgbà

Awọn opo ikansiraẹni lori itakun agbaye

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Awọn aṣofin n gbiyanju lati dẹkun bi awọn eeyan ṣe n pin iroyin ẹlẹjẹ lori itakun agbaye

Igbesẹ ijọba apapọ lati dẹkun bi awọn eeyan ṣe n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri lori itakun ayelujara ko buru, ṣugbọn, o ku nibọn n ro.

Dayo Akinlaja to jẹ agbẹjọrọ agba ati kọmiṣọna fun eto igbẹjọ nipinlẹ Ekiti tẹlẹ lo sọ ọrọ naa ninu ifọrẹowerọ pẹlu BBC lori koko ọrọ yii.

Ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja gunle abadofin kan, ti yoo ṣe iṣakoso bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n lo awọn opo ikansiraẹni lori itakun agbaye.

Erongba awọn aṣofin naa ni lati dẹkun bi awọn eeyan ṣe n pin iroyin ẹlẹjẹ kiri lori itakun agbaye.

Aṣofin agba Akinlaja sọ pe "O yẹ ki ijọba gbiyanju lati dẹkun awọn to ba n sọrọ to le da Naijiria ru lori ẹrọ ayelujara, sugbọn ijọba ko gbọdọ fi ẹtọ ara ilu lati sọrọ dun wọn."

facebook

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Oro lori ayelujara ti n fẹ amojuto lasiko yii

Akinlaja ni "ọmọ Naijiria lẹtọ lati sọrọ, sugbọn o yẹ ki wọn sọra fun ọrọ to lee ṣe ijamba fun alaafia ilu."

Àkọlé fídíò, Balogun market fire: Olubadamọran gomina sọrọ lori ina náà

Akinlaja gba awọn ọmọ Naijiria lamọran lati ṣe iwadii iroyin ti wọn ba gbọ ki wọn to gbe iru iroyin bẹẹ sori itakun agbaye, paapaa iroyin to lee ba elomiran lorukọ jẹ, ati eyi to le da ilu ru.

Àkọlé fídíò, Prepaid Meter: èrò àwọn èèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí 'sisan owó iná ní Nàìjíríà

Oluwatosin Ajibade, ti ọpọ eeyan mọ si "OloriSuperGal" sọ fun BBC pe, yoo sọro funn ijọba lati mu awọn to ba n pin iroyin ẹlẹjẹ kiri lori ẹrọmibanisọrọ wọn.

Ajibade pari ọrọ rẹ pe, ojuṣe gbogbo ọmọ Naijiria ni lati ri pe wọn ṣe iwaadi iroyin ti wọn ba gbọ lati ri daju pe ojulowo ni, ki wọn to pin kaakiri.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'