Naijiria ló gba ipò kẹwàá nínú orilẹ-ede tó ni ẹ̀gbin ju- Ìwádìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin kan ti sọ pe ilu Kano ni ilu to ni ìdọ̀tí inú afẹ́fẹ́ julọ ni gbogbo ilẹ Afirika- Switzerland.
Iwadii naa ni iwọn bi ilu naa ṣe dọti si le ni ida mẹtalelaadọta ninu ọgọrun un.
Gẹgẹ bi iroyin ọhun ṣe sọ, ohun mẹta lo jẹ ki ilu Kano wa ni ipo yii.
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí Sanwo Olu tó ní kí wọ́n máa pe òun ní "Ọ̀gbẹ́ni Gómìnà"
- Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ń bàjẹ́..; Akẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ 12 gbà èèyàn láti kọ ìdánwò fún wọ́n
- Òògùn tọ́jọ́ fẹ́ lọ lórí wọn ni àjọ SACA ń rà lábẹ́ àkóso aya Ajimobi - Seyi Makinde
- Ó ṣe jẹ́ ṣọ́ọ́bù aláṣọ kanṣoṣo ni iná tí maa ń ṣẹ́yọ lọdọọ́dún lọ́jà Balogun?
Iwadii naa ṣafihan ohun to mu Kano ni idọti inu afẹfẹ ati ayika to pọ yii pe:
Akọkọ ni pe pupọ ninu awọn olugbe ilu naa lo n fi igi, epo kerosin ati eedu da ina.

Oríṣun àwòrán, others
Ikeji ni bi awọn ojuko idalẹsi ṣe pọ kaakiri ipinlẹ Kano pẹlu idọti gọbọi.

Oríṣun àwòrán, World Air Quality report
Idi kẹta ni eefin to n wa lati ara ọkọ oju popo, alupupu ati awọn ohun miran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin naa wa fi kun un pe ilu Kampala, to wa ni Uganda lo wa ni ipo keji ninu awọn ilu to dọti ju, lẹyin naa ni ilu Port Harcourt ni guusu Naijiria tẹle.
- Bí alárùn Ebola bá wọ Nàíjíríà, kò sí gìrì, a ti múra sílẹ̀ láti paná rẹ̀ - Àjọ NCDC
- Olujinmi ló borí ìbò fẹ́kùn gúúṣù Ekiti, Adeyeye gba ile lọ - Iléejọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ṣèdájọ́
- Osinbajo kìí ṣe amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Buhari tí yóò máa gbé ìwé lọ fun ní London - Akin Alabi
- Sisitá ìjọ Kátólíkì méjì wá ṣe iṣẹ́ ìhìnrere l‘Afirika, lóyún bá dé
Iwadii ti ileeṣẹ IQ Airvisual to wa lorilẹ-ede Switzerland ṣe lo fi id iroyin naa mulẹ, to si fi orilẹ-ede Naijiria si ipo kẹwaa ninu awọn orilẹ-ede to ni ìdọ̀tí inú afẹ́fẹ́ ju lagbaye.

Oríṣun àwòrán, World air Quality
IQ Airvisual ni iwọn idọti ti orilẹ-ede Naijiria ni le ni ida mẹrinlelogoji ninu ida ọgọrun un, ti orilẹ-ede Uganda ati Ethiopia si n tẹle e lẹyin.
Iroyin naa ni ilẹ Afirika lo ni awọn ilu to n dagba soke julọ lagbaye nitori pe awọn olugbe ibẹ n pọ sii lojoojumọ, eyi lo mu ki idọti ọhun pọ to bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin ọhun wa fi kun un pe orilẹ-ede Bangladesh lo ni afẹfẹ to buru ju lati mi sinu julọ, nigba ti Pakistan ati India wa ni ipo keji atyi ẹkẹta.














