Exam Malpractices: Fọ́tò inú káàdì ìdánimọ̀ ló mú kí àkàrà tú sépo

Nigeria student

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Exam Malpractices: Fọ́tò inú káàdì ìdánimọ̀ ló mú kí àkàrà tú sépo

Aye n bajẹ ọmọ ole n kajọ. Ki ni ka ti ṣe iru eyi si, nigba tawọn akẹkọọ ile iwe alakọbẹrẹ ba n gba eeyan kọ idanwo wọn?

Bẹẹ lawọn eeyan n ṣemọ bi iroyin ti ṣe kan pe, ọwọ ọlọpaa tẹ awọn akẹkọ ile iwe alakọbẹrẹ mejila, ti wọn gba eeyan lati ba wọn joko ṣe idanwo aṣekagba wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin ta gbọ ni pe, awọn akẹkọ lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ Sese Bugolo gba awọn akẹkọ naa lati ile ẹkọ girama to wa ni agbegbe Buike ati Mukono ni orilẹede Uganda, lati ba wọn kọ idanwo.

Ọga agba feto ẹkọ lagbegbe naa, Hassan Nkutu ṣalaye lọjọ Iṣẹgun pe, n ṣe laṣiri awọn akẹkọọ naa tu nigba tawọn ri pe aworan ori iwe idanimọ wọn ko papọ mọ ti awọn to n kọ idanwo.

Awọn akẹkọ ileewe alakọbẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Other

Hassan sọ pe ''ọkan lara awọn ọtẹlẹmuyẹ ta ni ko mojuto idanwo naa lo ri awọn afunrasi ohun. N ṣe la ri pe aworan to wa lori kaadi idanimọ wọn ko papọ mọ eleyi ti ile iṣẹ eto ẹkọ Uganda pese''

Agbẹnusọ ọlọpaa lagbegbe naa, Hellen Butoto sọ pe awọn yoo kesi awọn adari ile iwe naa lati wa ṣalaye ohun to ṣẹlẹ.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'