Prepaid Meter: èrò àwọn èèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí 'sisan owó iná ní Nàìjíríà
Ọrọ to n lọ bayii- ọrọ lori mita ina mọnamọna!
Ọrọ ina mọnamọna ni Naijiria ti ko si ni ọpọlọpọ awọn agbegbe ati owo gọbọi ti wọn n mu wa fara ilu ni wakati perete to ba fi wa lo n kọ ọpọ eeyan lominu lasiko yii.
Ọrọ to n lọ jẹ eto akanṣe ti BBC Yoruba a fi maa gba ẹdun ọkan awọn eniyan lori koko to ba n dùn wọn lọkan.
Ọpọ ọmọ Naijiria fi ibanujẹ wọn han lori ina ọba ti kii si ati owo to ga ju agbara lọ ti awọn oniṣẹ mọnamọna n muwa fun wọn loṣooṣu.
Bi awọn kan ṣe ni ko yẹ ki ki awọn eniyan maa sanwo gọbọi lori mita ti wọn n ka lẹyin tijọba ti ni ki wọn pin mita oniwiwọn fun odiwọn ina ti onikaluku ba lo;
Bẹẹ naa ni awọn miran ni ki ijọba ṣi maa fun wọn ni biili afojusun ṣugbọn ko ma ga ju ara lọ.
- Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ń bàjẹ́, à ló ń pọ́n! Akẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ 12 gbà èèyàn láti kọ ìdánwò fún wọ́n
- Òògùn tọ́jọ́ fẹ́ lọ lórí wọn ni àjọ SACA ń rà lábẹ́ àkóso aya Ajimobi - Seyi Makinde
- Bí alárùn Ebola bá wọ Nàíjíríà, kò sí gìrì, a ti múra sílẹ̀ láti paná rẹ̀ - Àjọ NCDC
- Ó ṣe jẹ́ ṣọ́ọ́bù aláṣọ kanṣoṣo ni iná tí maa ń ṣẹ́yọ lọdọọ́dún lọ́jà Balogun?
Ni ipari, Felix Ofulue to jẹ aṣoju ileeṣẹ ina mọnamọna ni Ikeja ni ipinlẹ Eko di ẹbi ọrọ yii ru alakalẹ ijọba lori ina pinpin to pọju paapaa lori mita piripeedi.
O gba awọn eeyan nimọran pe ko tọna lati má sanwo ina ti wọn n lo rara.
- Olujinmi ló borí ìbò fẹ́kùn gúúṣù Ekiti, Adeyeye gba ile lọ - Iléejọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ṣèdájọ́
- Osinbajo kìí ṣe amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Buhari tí yóò máa gbé ìwé lọ fun ní London - Akin Alabi
- Ẹ̀yin òbí, ẹ má kó àwọn ọmọ yín lọ síbùdó atúnwàṣe mọ́ - Seyi Makinde
- 'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'