Seyi Makinde gbàlejò Abdulsalami Abubakar ní Ibadan

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Oyo state

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti se apejuwe adari orilẹede Naijiria nigba kan ri, Abdusalami Abubakar gẹgẹ bi baba to ni ifẹ si ilosiwaju orilẹẹde Naijiria.

Seyi Makinde sọ eyi lasiko to n gbalejọ Abubakar Abdusalami ni ilu Ibadan.

Makinde ni ijọba ti setan lati se ohun gbogbo to yẹ lati ri wi pe eto aabo gbooro si ni ipinlẹ Ọyọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Abdusalam, nigba to n fesi, gboriyin fun gomina Makinde, to si ni ọgbọn ati imọ to n lo nigba to n sisẹ aladani yoo ran an lọwọ lati tukọ ipinlẹ naa de ibi aseye.

Adari Naijiria nigba kan naa wa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati ri wi pe wọn seto igbaye gbadun fun awọn olugbe ipinlẹ naa.

Ọgaagun Abdulsalami Abubakar jẹ adari orilẹede Naijiria ni ọdun 1998 si ọdun 1999.

OYO STATE

Oríṣun àwòrán, OYO STATE

Àkọlé àwòrán, Ọgaagun Abdulsalami abubakar jẹ adari orilẹede Naijiria ni ọdun 1998 si ọdun 1999.

Seyi Makinde ati Adari Ile Asofin Ipinlẹ Ọyọ, Adebo Ogundoyin lo fi tọwọtọwọ ki Abdusalami Abubakar kaabọ si ipinlẹ naa.

Gomina naa si fi ami ẹyẹ aworan ti wọn fi owo ya, da ajagunfẹyinti naa lọla.

OYO STATE

Oríṣun àwòrán, Oyo State