FIFAWWCUP: Wo ohun mẹ́rin tó jẹ́ ki America tún gbá ife ẹ̀yẹ àgbáyé

Megan

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ta ni ẹlẹ́sẹ̀ ayò Megan Rapinoe tó gba ife ẹyẹ àgbáyé tàwọn obìnrin?

Èyí ni ìgbà kẹrin tí America yóò gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé nínú ìdíje tàwọn obìnrin tí kò ṣẹ̀yìn Rapinoe tó gba bàtà gòólù.

Megan Rapinoe ni Balogun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu obinrin fun orilẹ-ede America lọdun 2019.

Repinoe lo gba ami ẹyẹ ẹlẹsẹ ayo bata goolu, bọọlu goolu àti agbabọọlu to fakọyọ julọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye tawọn obinrin to pari ni France yii.

Wo ohun to yẹ ki o mọ nipa ẹni ti Megan Rapinoe jẹ?

Igba ikeji ni yii ti Megan maa gba ife ẹyẹ agbaye tawọn obinrin lọ sile gẹgẹ bii balogun ikọ USA.

Oun lo kọkọ gba bọọlu sáwọ̀n Netherland ninu idije aṣekagba naa ni papa iṣere Lyons eleyii to sọ USA di olu ọmọ ninu idije naa.

Ọpọ ṣẹṣẹ gbagbọ nipa imọsilara rẹ pẹlu ajọṣepọ akọ si akọ ati abo si abo nigba ti o kigbe pé " Go Gays" - Akọ si akọ; abo si abo, ẹ tẹsiwaju.

Àkọlé fídíò, 'Góòlù tí mo fẹ́ràn ní World Cup'

Irun alawọ rẹsurẹsu ni aawọ irun ori ẹlẹsẹ ayo Megan eyi ti ọpọ obinrin si ti ni wọn yoo sọ aawọ irun ori wọn da lẹyin idije naa.

Megan Rapinoe jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelọgbọn to ti wa lẹnu owo bọọlu gbigba lọdun melo sẹyin.

O ti gba bọọlu fun ẹgbẹ oriṣii meje ni ọpọlọpọ orilẹ-ede agbaye.

Megan ti gba ami ẹyẹ bii ti NWSL Sheild pẹlu Reign FC lẹẹmeji yatọ si ti goolu olimpiiki ati ti ife ẹyẹ agbaye ẹẹmeji bayii.

Àkọlé fídíò, Fídíò BBC yọ àwọn èèyàn FIFA níṣẹ́ ṣááju Russia 2018

Megan jẹ ẹni to fẹran lati maa ṣe nkan tawọn eniyan a maa sọrọ le lori lẹyin idije.

Bi apẹẹrẹ ninu idije tọdun 2011, o gba ẹrọ gbohungbohun lori papa ni kete to gba bọọlu sáwọ̀n Columbia ki wọn to koju Japan nibi to ti kọrin nipa ibi rẹ ni Amerika.

america

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awa America la tun gba ife tọdun 2019

Megan ni awọn amohunmaworan ṣafihan rẹ pe ko kọ orin ogo ilẹ Amerika jade ṣaaju idije wọn.

O wa lara awọn ti wọn n ja pe ki ajọ FIFA sọ owo idije obinrin di iye kan naa pẹlu ti ọkunrin ni agbaye nitori bi a ṣe bi ẹru ni abi ọmọ.

Àkọlé fídíò, Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù

Wo ohun mẹ́rin tó jẹ́ ki America tún gbá ife ẹ̀yẹ àgbáyé

Orilẹ-ede America ati Netherland ni wọn jọ gbena woju ara wọn ninu idije aṣekagba ti awọn obinrin lagbaye lọdun 2019.

Ami ayo meji sodo ni wọn fi gbe ifẹ ẹyẹ lọ ti wọn fi na Netherland.

Àkọlé fídíò, Fulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀

Orilẹ-ede France lo gba alejo idije tọdun 2019 naa.

America naa lo gba ife ẹyẹ naa lọdun 2015, fun idi eyi ilé ni wọn tun gbe e pada si.

Ẹkọ mẹ́rin ti a lè kọ́ lára America:

1) Ko si ìgbà ti a ko le da aṣọ ki a tun fi wọ́lẹ̀ pẹlu iyì: Kii ṣe dandan ko jẹ pe ninu abala idije akọkọ ni ẹgbẹ agbabọọlu ti le yege ninu idije.

Abala keji idije aṣekagba laarin Netherlands ati America ni Megan Rapinoe ati Rose Lavelle ti jẹ goolu to mu ki America gbe igba oroke ninu idije naa.

2) O ṣe pataki fun ẹgbẹ agbabọọlu to ba fẹ ṣe aṣeyọri lati ni adilemu to gbounjẹfẹgbẹ gba awo bọ.

Sari Van Veenendaal to jẹ adilemu fun America mọ iṣẹ rẹ bii iṣẹ.

Ẹẹmẹrin ọtọọtọ lo mu bọọlu ti ko ba di goolu mọ wọn lọwọ ni eyi ti wọn ko ba fi di apẹrẹ ajaṣẹ ninu idije ife ẹyẹ agbaye naa.

3) Ọpọ igba ni eeyan le goke ọla to ba ni ipinnu lai wo aṣeyọri latẹyinwa.

Ẹgbẹ agbabọọlu Amerika ko roo pe awọn ti gbe ife ẹyẹ naa lọ ri lọdun 1991, 1999 ati 2015.

Wọn tẹpa mọṣẹ lati ibẹrẹ idije naa pẹlu ipinnu lati tun gba ife ẹyẹ naa lọdun yii, eyi to pada wa si imuṣẹ fun wọn ni papa iṣere Lyon ni orilẹ-ede France.

Àkọlé fídíò, Wo imọran Fọlọrunṣọ Alakija fun awọn ọdọ adulawọ

4) Agbajọwọ la fi n sọya, ajoji ọwọ kan kò gbéru dori lo n di aṣeyọri ẹnikọọkan ninu idije.

Rapinoe to pada jẹ ọkan ninu goolu to mu ki Amerika na Netherland ko deede ri goolu naa jẹ, awọn kan ni wọn gba bọọlu naa titi to fi de ẹsẹ tirẹ.

Goolu yii lo jẹ ki Rapinoe pada gba ami ẹyẹ ẹlẹsẹ ayo goolu ninu idije todun 2019 yii.

Eyi jẹ ki goolu rẹ pe mẹfa ti oun funra rẹ si ran awọn meta lọwọ lati jẹ goolu ninu idije ife ẹyẹ agbaye naa.

Àkọlé fídíò, CAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria

Bakan naa ni Rapinoe gba ami ẹyẹ bọọlu oni goolu pe oun lo mọ ọ gba julọ ninu idije ọdun 2019.

Sibẹ ọpọlọpọ gba pe amulumala agbara ọdọ ati awọn to ti ni iriri ni akọnimọọgba Amerika lo to fi gba ife ẹyẹ tọdun 2019.

Àkọlé fídíò, Osun Supreme: Àwọn èèyàn Ọṣun rọ Oyetọla láti jẹ́ kí àsìkò rẹ̀ tú aráàlú lára