CAF Champions League: CAF pàṣẹ àtúngbá ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àṣekágbá CAF Champions League

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ṣakoso ere bọọlu afẹsẹgba ni ilẹ Afirika, CAF ti paṣẹ ki wọn tun ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije CAF Champions league to waye ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu karun ọdun 2019 gba.
Bi o tilẹ jẹ pe igbesẹ ati aṣẹ ọhun ṣe ọpọlọpọ onwoye ere bọọlu afẹsgba ni haa-hinn, ajọ CAF ni bi eto ati ato gbogbo ṣe lọ si lasiko ifẹsẹwọnsẹ naa ku diẹ kaa to eyi lo si faa ti oun fi gbe igbesẹ atungba ifẹsẹwọnsẹ naa.
- FIFA yan Infantino gẹ́gẹ́ bí ààrẹ fún sáà kejì
- Mi ò ní gbà! Joshua àti Ruiz gbà láti jàjà mííràn lóṣù kọkànlá
- Liverpool da ata gúngún sójú Tottenham gba ife ẹ̀yẹ Champions League
- 'Ọmọ SS 1 mu èso olómi, ṣùgbọ́n ilé ìwé wa kọ́ ló kú sí'
- Owó wọgbó! Gẹ̀ẹ́sì gbẹ́sẹ̀ lé ₦82bn owó Abacha
- Aisha, bá ọ̀kọ̀ rẹ sọ̀rọ̀ ní yàrá lórí ìpèníjà ètò ààbò - Obasanjo
Nibi ipade igbimọ alaṣẹ ajọ CAF to waye ni ilu Paris lorilẹede France lọjọru ni aṣẹ yii ti jade.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lara awọn ohun ti gbogbo ọmọ igbimọ naa fẹnuko si ni iwọnyii:
- Eti fun irọwọrọsẹ idije naa ati abo ko peye lasiko ipele keji aṣekagba idije CAF Champions league to waye ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu karun ọdun 2019 eyi ti ko fi aaye silẹ fun ifẹsẹwọnsẹ naa lati wa si opin gẹgẹ bi ofin ere bọọlu ṣe laa silẹ.
- Nitori idi eyi, wọn gbọdọ tun ifẹsẹwọnsẹ naa gba ni papa iṣire miran ti ko ni jẹ ti orilẹede Tunisia;
- Igbimọ alaṣẹ ajọ CAF yoo gbe ọjọ ati ibi ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo ti waye sita laipẹ;
- Nitori idi eyi, ẹgbẹ agbabọọlu Espérance de Tunis gbọdọ da ife ẹyẹ ati awọn ami ẹyẹ gbogbo ti wọn fun wọn pada si olu ileeṣẹ ajọ CAF lẹyẹ o ṣọka;
- Gbogbo awọn ọrọ gbogbo to ku lori ibawi, ato ati bi awọn oludari ere bọọlu yoo ṣe ri yoo tẹ awọn igbimọ gbogbo to ba yẹ lọwọ fun igbesẹ ati ipinnu wọn.









