FIFA: Infantino máa bá'ṣẹ́ rẹ lọ

Gianni Infantino

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn ti tun yan Gianni Infantino lẹ́ẹ̀kan síi gẹgẹ bi aarẹ ajọ to n moju to ọ̀rọ̀ bọọlu alafẹsẹgba lagbaye, FIFA.

Ẹni ọdun mọkandinlaadọta ara Italy naa yoo wa lori alefa titi di ọdun 2023 lai ni alatako kankan.

Infantino lo gba eku ida lọwọ Sepp Blatter lọdun 2016 to si ti mu afikun ba iye awọn agbabọọlu ti yoo figagbaga fun ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye lọdun 2026.

Àkọlé fídíò, Pẹ̀lú gbogbo bùkátà, Bàbá 80 gboyè Masters

Ọdun mẹtadinlogun ni aarẹ tẹlẹ, Blatter fi wa lori alefa ti wọn fi gbọn ọn yọ latari ẹsun iwa jẹgudujẹra lọdun 2015 ti Infantino si bẹrẹ iṣẹ lọdun 2016.

Ṣe latẹwọ n ro nibi ti wọn ti tun Infantino yan lẹyin ti ayipada ofin wa pe ko ma tun si eto idibo mọ niwọn igba to ba ti jẹ pe oludije kan ṣoṣo lo wa.

Ninu ọrọ rẹ, Infantino gbe iṣejọba tirẹ wo lẹgbẹkẹgbẹ ohun to jogun ba.

Àkọlé fídíò, 'Mo ń ṣa ike jọ láti san owó ilé iwé ọmọ mẹ́ta'

O ni "ko sẹ́ni to n sọrọ wahala mọ tabi ṣiṣe atunto FIFA lati isalẹ, ọrọ bọọlu nikan lo ku ti a maa n sọ. Infantino ni awọn lee sọ pe awọn ti yi nkan pada si rere.

Ajọ to ti baba dibajẹ, to fi mọ didi agbo ọdaran lo ti wa pada bọ sipo si ohun to yẹ ko jẹ iyẹn ajọ to n mu agbega ba bọọlu alafẹsẹgba o si ti wa di eyi to ni ọwọ mimọ ati ootọ inu.

Infantino to jẹ akọwe ajọ Uefa tẹlẹ lo wa lẹyin imugboro ife ẹyẹ agbaye lati ikọ agbabọọlu mejilelọgbọn si mejidinlaadọta ti yoo dije lọdun 2026 ti yoo waye ni orilẹede America, Canada, Mexico.

Ninu oṣu kẹta ajọ FIFA buwọlu aatọ Infantino fun ikọ agbabọọlu ẹlẹni mẹrinlelogun ti yoo bẹrẹ lọdun 2021 bi o tilẹ jẹ pe awọn ikọ agbabọọlu ilẹ Yuroopu to lokiki ni awọn ko ni yẹ idije naa.