PDP: Buhari gbọdọ̀ tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ ọmọ Nàíjíríà fún èdè àbùkù tó pè

Oríṣun àwòrán, @Buhari official
Ìsọ̀rọ̀ ní ìgbèsì, ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) ti fẹ̀sì si ọ̀rọ̀ ààrẹ Muhammadu Buhari to ni "Eni ibi ti kò ṣe máà nìí ni àwọn ènìyàn Abuja".
Ẹgbẹ́ alátakò PDP ni, kìí ṣe ohun tó tọ́ ni ki ààrẹ maa bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn olùgbé ìlú Abuja nítori pé wọn kò láti dibò fún nínú ìdìbò aààrẹ tó wáye nínú oṣù kejì ọdún 2019.
Akọ̀wé ìpolongo gbogbogbò fún ẹgbẹ́ PDP, Kola Ologbondiyan nínú àtẹjade to fi síta, salaye pé ìwà ki ààrẹ maa fún ará ìlú ni orúkọ ti ko dára kìí ṣe ohun tó bojumu.
Ologbondiyan ni, nítori pé awọn araalu ṣe ẹ̀tọ́ wọn nínú ìfẹ́ ọ̀kan wọn, kìí ṣe ǹkan ti ko bójú mu rárá.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Gẹ́gẹ́ bóṣe sọ, ìpedè Buhari yii jẹ́ èyí to le dá wàhalà sílẹ̀ láàrin ìlú, ó wa ke pe Buhari láti tọrọ àforijì lọ́wọ́ àwọn ọmọ Naìíjríà fún irú èdè bẹ́ẹ̀.
Ologbondiyan ni " ó ṣe pàtàkì ki ààrẹ Buhari mọ̀ pé kìí ṣe àwọn ará Abuja nìkan ló kọ̀ ọ́, bíkòṣe ogúnlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ti wọ́n dibo fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, kí óto di pe àjọ elétò ìdìbò yí ìpinu àwọn ara ilú padà.
O fí kún pé ààbo àrá ìlú ló yẹ ko ṣe pàtàkì sí ààrẹ, kìí ṣe àwọn irú ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu ààrẹ jáde.
Buhari: Ẹni ibi tí kò ṣeé má ní làwọn ará Abuja

Oríṣun àwòrán, Presidency
Lerefe ni aarẹ Muhammadu fi ọrọ ran Senator to n ṣoju olu ilu orilẹede yii, Phillip Aduda sí awọn ara ilu Abuja pe ẹni ibi ni wọn ṣugbọn oun ko le ṣai ma tọju ilu Abuja.
Eyi waye nile ijọba lọjọ iṣẹgun ọsẹ yii nigba ti igakeji aarẹ Osinbajo dari Sẹnetọ Phillip pẹlu ikọ aṣoju kan lati olu ilu Abuja lọ ki aarẹ sile fun ti ọdun Sallah.
Aarẹ ni ki Osinbajo tọju ara rẹ o ki aarẹ ma daa lulẹ tori ailokun rẹ lee mu ailokiki ba ijọba to wa lori alefa ti awọn eniyan ko si ni mọ riri iṣẹ takun takun ti awọn n ṣe.
Ẹwẹ, aarẹ ni oguna gbongbo ni olu ilu orilẹede yii, Abuja jẹ ni Naijiria eyi ti iṣejọba oun yoo mu ọrọ wọn lọkunkundun bi o tilẹ j pe wọn ko dibo fun oun ninu idibo to kọja lọ.
Aarẹ ṣapejuwe awọn olugbe ilu Abuja gẹgẹ bii "awọn eeyan buburu ti ko ṣee ma ni".
O sọ fun sẹnetọ Pilip Aduda pe ẹkun idibo tirẹ gan(Phillip) ko dibo fun oun(Buhari).
Iroyin tun sọ pe aarẹ sọ wi pe "mo ni gbogbo esi idibo ẹkun jẹkun lọwọ".
Aarẹ Buhari ni "mi o dẹru ba olu ilu yii o nitori bi mo da abo bo Abuja, ara mi ati igbakeji mi naa ni mo da abo bo".
"Ṣugbọn o dami loju pe wọn mọ pe ẹni ibi ti ko ṣee ma ni niwọn".
Aarẹ wa dupẹ lọwọ awọn to ti i lẹyin fun ifọkansin wọn o si ṣeleri lati ṣe gbogbo daadaa to ba le ṣe ni saa tuntun yii.
Igbakeji aarẹ Osinbajo ni tirẹ ki aarẹ Buhari ku oriire opin awẹ Ramadan, o ni Ọlọrun dara si aarẹ ati ijọba gan ni.
Osinbajo ni "lootọ iyatọ le wa laarin awn ọmọ Naijiria ni ti ẹsin tabi ẹya ṣugbọn oṣuṣu ọwọ kan naa ni wa".
Ọgbẹni Christian Oha to jẹ akọwe ile iṣẹ to n ri si ọrọ olu ilu orilẹede yii, ki aarẹ ku oriire lori eto iburawọle rẹ wọn ṣe adura fun un wọn si jẹjẹ atilẹyin wn fun aarẹ Buhari pe gbọingbọin lawọn ara Abuja wà lẹyin aarẹ ni saa to ti wọle yii.
















