World Environment Day: Atẹ́gùn burúkú ń pa mílíọ̀nù 8.8 ènìyàn ni ágbáyé, ọ̀pọ̀ nínú wọn ọmọdé

Kẹkẹ ati arakunrin kan n kọja nibi ti eefin wa ni ilu Port Harcourt.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Eefin Port Harcourt ti di oun to n ba gbogbo eniyan to ba de ilu naa lẹru

Ajọ ilera agbaye WHO ni Naijiria wa lara orilẹede ti atẹgun oró ti n pa awọn eniyan ju.

Ninu iwadii ti ajọ naa ṣe, wọn fi han wipe orilẹede Naijiria ni ikẹrin ni agbaye ti atẹgun buburu ti n pa awọn eniyan ju. Ko da, ajọ naa ni, ti a ba ko ẹgbẹrun lọna ọgọrun ọmọ Naijiria jọ, aadọjọ ninu wọn ni atẹgun ti ko dara yoo gbẹmi rẹ.

Ọrọ yii tun di ohun a n tana wo loni to jẹ ayajọ ọjọ ayika ti wọn ṣi n mẹnu ba ọrọ atẹgun buburu tabi atẹgun ti ko mọ ni ayika eniyan.

Ninu iwadii WHO, aworan isalẹ yii fi han awọn orilẹede ti atẹgun ti buruju. Awọn agbegbe to ni awọ pupa ni atẹgun wọn buruju. Awọn to nii awọ ewe lo dara ju ti alawọ yẹlo ko si buru to awọn to ni awọ pupa.

Awọn orilẹede to ni atẹgun to buruju ni agbaye

Oríṣun àwòrán, WHO

Àkọlé àwòrán, Ajọ ilera agbaye ni Naijiria wa lara orilẹede ti atẹgun oró ti n pa awọn eniyan ju.

Iwadii awọn onimọ sọ wipe, atẹgun awọn ilu bii Eko, Port Harcourt, Abuja ati Kano lọpọ gbedeke ti WHO gba laaye ni ilọpo ọna, eyi to si n ṣe iku pa awọn ara ilu.

Ajafẹtọ ọmọ eniyan lori ọrọ ayika, Rev. David Ugolor ni epo buruku ti awọn to n gbepo rọbi wọ Naijiria fun lilo awọn ọkọ jẹ ọkan lara ohun to n ba atẹgun orilẹede yii jẹ.

Ko da, Ugolor ni awọn epo ti wọn n gbe wọ Naijiria buru lọna ọọdurun ju eyi ti wọn n lo ni Yuroopu lọ.

Ṣugbọn ni oṣu keje ọdun 2017, ijọba apapọ fofin de iru awọn epo ti ko dara wọn yii nitori ọpọlọpọ iwọn sọ́fọ̀ (sulfur) to wa ninu rẹ.

Ọkọ kan ti eruku n jade ninu rẹ
Àkọlé àwòrán, Ijọba fofin de awọn ileeṣẹ elepo to n gbe epo ti ko dara wọ Najiria.

Ṣugbọn ni orilẹede Naijiria, ọpọ nnkan lo n fa atẹgun ti ko dara.

Ni ilu Port Harcourt, eefin ileeṣẹ epo rọbi ti di ohun ti awọn ara ilu fi n ke gbajare si ijọba, ṣugbọn ọrọ naa ko ti i ni iyanju.

Eefin awọn ileeṣẹ epo rọbi ni Nigeria

Oríṣun àwòrán, AFP

Pẹlu gbogbo awọn ọna ti atẹgun oró fi n de inu agọ ara ọmọ Naijiria yii, awọn onimọ ti ke si ijọba ki wọn gbe igbesẹ gboogi lati dẹku iku to n pa awọn ọmọ Naijiria lati awọn ọna wọnyii.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ si: