Guru Maharaji: Ó yẹ kí ìjọba àpapọ̀ fíkún owó oṣù òṣìṣẹ́ àti ti adájọ́

Aworan Guru Maharaji
Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Buhari fí mí jẹ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì lóri epo rọ̀ọ̀bì- Guru Maharaji

Ohun tó ba ń dun ni, ṣebí wọ́n ni òhun ló máa ń pọ̀ lọ́rọ́ ẹni, adari àti olùdásilẹ̀ One Love Family, Sat Guru Maharaji ti ke pe ààrẹ Muhammedu Buhari, láti yan òun gẹ́gẹ́ bi olùbádámọ̀ràn pàtàkì fọ́rọ̀ epo rọ̀bi.

Maharaji kesi aarẹ Buhari bẹẹ, lasiko ipade akọroyin to se eyi to fi n sami ajọdun ọdun kẹrindinlọgbọn to kede Naijiria bii ilẹ mimọ lagbaye.

Maharaji ní èyí se pàtàkì gẹ́gẹ́ bi àwọn ẹlẹ́sìn àti olóri ẹ̀sìn to kù ṣe ń kùnà, ó ní ọ̀kan nínú àwọn èròńgbà òun ni pe kí ààrẹ yan òun láti máá moju to ile iṣẹ́ ọ̀rọ̀ omi àti àlùmọ́ni, ilé iṣẹ́ ọ̀gbìn àti ọ̀rs epo rọ̀ọ̀bi àti afẹ́fẹ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Yàtọ̀ si èyí, Guru Maharaji ní ó yẹ ki ìjọba àpapọ fí kún owó oṣù òṣìṣẹ́, kí wọ̀n si mú kí ìgbáyégbádùn àwọn adájọ lọkunkundun, kí wọ́n ma ba máá ṣe ojúkokoro láti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

Àkọlé fídíò, Ladoja: Àwọn èèyàn Oyo fì ìbò sọ̀rọ̀ pé ìjọba Ajimobi kò dára

Olórí ẹ̀sin ọ̀hun ní, o ṣe pàtàkì ki wọ́n se ìdásílẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ nítori pe, èyí yóò mú ki ààbò to dáju wà láárín àwùjọ.